OsunDecides: Olùdíje fún igbákejì gómìnà fẹ́gbẹ́ ADC ní àwọn yóò pèsè ọ̀pọ̀ isẹ́ l‘Ọ́sun
Adájọ́-fẹ̀yìntì Ọlamide Oloyede, tíí se olùdíje fún ipò igbákejì gómìnà fẹ́gbẹ́ òsèlú ADC l‘Ọ́sun, lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ní, ìgbìnyànjú òun ni láti máa pe àkíyèsí àwọn olórí sí ẹ̀jẹ́ tí wọn jẹ́, láti mú ìgbáyé-gbádùn bá ará ìlú.
Adájọ́-fẹ̀yìntì Oloyede fikun pé, òfin African Growth Development Act tí Nàíjíríà pa tì láì lò, ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wà nínú ìsẹ́ àti òsì.
Olùdíje fún ipò igbákejì gómìnà fẹ́gbẹ́ òsèlú ADC l‘Ọ́sun náà wá fọwọ́ gbáyà pé ẹgbẹ́ òsèlú ADC yóò pèsè isẹ́ lọ́pọ̀ yanturu fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.