OsunDecides: Omisore ní ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò, àwọn yóò lọ lásọ mú ni
Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Social Democratic Party (SDP) ni ipinlẹ Ọsun, Sẹnetọ Iyiọla Omisore, lasiko to n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ni, ẹgbẹ alatako ni yoo bori ibo gomina ni ipinlẹ Ọsun, gẹgẹ bo se waye ni Ekiti, nitori isejọ̀ba ẹgbẹ to wa lori aleefa ti su awọn ara ilu.
Omisore ni, owo ti ijọ̀ba Ọsun ń gba lati ọ̀dọ̀ ijọba apapọ to lati fi san owo osu osisẹ, ti ko si si idi kankan fun ijọba Ọsun lati jẹ́ awọn osisẹ́ lowo osu.
Bakan naa lo jẹjẹ pe awọn ọmọ oselu SDP yoo duro pa lati sọ ibo wọn ni, tawọn yoo si lọ ẹnikẹni to ba ko owo wa si agọ idibo, lati ra ibo, ni asọ mu ni.