You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
World Cup 2018: Nàíjiríà kọ̀ le e gbé adiye wọ Russia
Awọn ololufẹ bọọlu ilẹ Naijiria beere fun aaye lati gbe adiyẹ laaye wọ ori papa isẹrẹ ni Russia lasiko ifẹsẹwọnsẹ laarin Naijiria ati Croatia.
Minisita fun ọrọ aṣa ati iṣe ni orilẹ-ede Russia, Andrei Ermak, lo sọ bẹẹ fun awọn akọrọyin lasiko igbaradi fun Ife Ẹyẹ Agbaye 2018.
Ermak sọ pe awọn ko le e fun awọn ololufẹ bọọlu lati orilẹ-ede Naijiria laaye lati gbe adiye wo ori papa ni gbogbo igba ti Naijiria ba ti n gba bọọlu lori paapa.
Minisita naa fikun wi pe papa isere ti Naijiria ti fẹ gba ni Ọjọ Satide pẹlu Croatia ni Kaliningrad ti yoo gba ọpọlọpọ eniyan lasiko naa.
Ikọ̀ Super Eagles ti Nàìjíríà yóò fẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú Croatia lọ́jọ̀ Sátidé níbi Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé ti Russia 2018 tó ń lọ lọ́wọ́
Nigba ti Egypt ati Uruguay yoo waa ko lọsan oni.