Ìsèjọba Nàíjíríà: Bí ológun se lọ, ni alágbádá wọlé dé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Naijiria gba ominira lọwọ ijọba ilẹ Gẹẹsi ni ọjọ kinni osu kẹwa ọdun 1960.
Aarẹ akọkọ ni orilẹede Naijiria ni Nnamdi Azikwe, ti Abubakar Tafawa Balewa si jẹ Olori ijọba.
Naijiria di orilẹede olominira ni ọdun 1963.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí
Aarẹ Azikwe ati Olori ijọba Tafawa Balewa wa lori aleefa di ọdun 1966.
Ṣugbọn awọn ologun gba ijọba lọwọ rẹ l'ọdun 1966 kan naa.
Ọmọ ologun Chukwuma Kaduna Nzeogwu lo dari iditẹ gbajọba naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ologun bẹrẹ si ṣe ijọba orilẹede Naijiria lẹyin igbati olori ologun Aguiyi Ironsi gori aleefa .
Orilẹede Naijiria pada si ijọba awa-arawa ni ọdun 1979 nigbati olori ijọba ologun, ogagun Olusegun Obasanjo gbejọba fun ijọba alagbada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alhaji Shehu Shagari, to soju ẹgbẹ oselu NPN lo jawe olubori ninu idibo gbogbo-gboo fun ipo aarẹ l'ọdun naa.
Aarẹ Shagari ṣe 'jọba fun ọdun mẹrin akọkọ, o si tun wọle fun saa keji ni ọdun 1983.
Ṣugbọn ko pẹ to wọle ni awọn ologun tun gbajọba, ti ọgagun Ibrahim Babangida si gori aleefa.
Awọn ologun ṣe ijọba orilẹede Naijiria di ọdun 1999, ki ijọba tiwa n tiwa to pada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajagun fẹhinti Oluṣégun Obasanjo lo jawe olubori ninu idibo gbogbo-gboo fun ipo aarẹ bi Naijiria ṣe pada si ijọba awarawa l'ọdun 1999.
Ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa lori aleefa fun ọdun mẹrindinlogun akọkọ, ki APC to gori oye l'ọdun 2015 nigbati Aarẹ Muhammadu Buhari bẹrẹ ijọba rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Aarẹ Buahari pe ọdun mẹta l'ọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2018, ti i ṣe ayajọ ọjọ ijọba awarawa nilẹ Naijira.













