Ọ̀yọ́: Àwọn ọ̀dọ́ da ìdìbò káńsù ru ní Ìbàdàn

Ija ti bẹ silẹ ni agbegbe Olodo ni ilu Ibadan nibi ti ibo kansu ti n lọ lọwọ n'ipinlẹ Ọyọ.
Akọroyin wa ti o n tẹle bi nkan ṣe n lọ jábọ̀ pé, awọn ọdọ kan l'agbegbe naa sọ pe idibo ko ni waye ni ijọba ibilẹ Lagelu, afi bi wọn ba f'awọn lowo.
Ẹ̀wẹ̀, eto idibo naa ko di lilọ-bibọ ọkọ lọwọ.

Akọroyin wa sọ di mimọ pe, ko si idiwọ fun àwọn ọ̀kọ̀ to ń kọja loju ọna marosẹ ní Ibadan bi ibo ti n lọ lọwọ.








