Abiola Ajimobi: Idris yóò di Aare Akogun Musulumi ìpínlẹ̀ Oyo tuntun

Inu idunu ati ayọ ni awọn mọlẹbi gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi wa bayii lẹyin ti wọn gbọ pe ọmọ wọn Idris Ajimobi yoo di Aarẹ Akogun Musulumi ni ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọ Aiku, ọjọ Kẹjọ, oṣu Karun un, ọdun 2022 yii ni ifinijoye naa yoo waye niluu Ibadan.

Imaamu agba ilu Ibadan, Sheikh AbdulGaniyy Agbotomokekere ni yoo ṣe eto ifinijioye naa fun Idris ni mọṣalaṣi apapọ ilu Ibadan to wa ni Oja'ba.

Ipo Aarẹ Akogun Musulumi jẹ ọkan lara awọn ipo to ṣe pataki, to si niyi lawujọ awọn Musulumi, paapaa niluu Ibadan.

Ta ni Idris Ajimobi?

Idris Abolaji Ajimobi jẹ ọkan lara awọn ọmọ gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi to di oloogbe bayii.

Abiola Ajimobi jade laye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2020, lẹni aadọrin ọdun leyin aisan ranpẹ.

Idris jẹ ẹnikan ti ko fẹran lati maa gbe ara sita lori afẹfẹ, amọ ọpọ araalu mọ nipa rẹ lẹyin to gbe ọmọ gomina ipinlẹ Kano, Umar Ganduje ni iyawo loṣu Kẹta, ọdun 2018, iyẹn Fatima Ganduje.

Tọkọ-taya naa kede igbeyawo ọhun loju opo Instagram lọdun naa lọhun ki igbeyawo naa to waye.

Gẹgẹ bii baba rẹ, oloṣelu ni Idris Ajimobi.

O si wa lara awọn to n dije du ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ninu eto idibo gbogbogbo ti yii waye lọdun 2023.