You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dowen College: Ààrẹ Buhari ní gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Sylvester Oromoni kò ní lọ láì jìyà lábẹ́ òfin
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ko si ẹnikẹni to lọwọ ninu iku akẹkọọ Dowen College, Sylvester oromoni, ti yoo lọ lai foju wina ofin.
Buhari lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi lede loju opo Facebook rẹ.
Atẹjade naa ni Aarẹ Buhari koro oju si bi awọn kan ṣe pa Sylvester to jẹ ogo ọjọ ọla idile rẹ, ati pe ijọba yoo fi imu awọn to lọwọ ninu iku rẹ dọrin to bẹẹ ti eyii yoo jẹ aṣemọ wọn.
- Mọ̀ síi nípa abẹ́rẹ́ àjẹsara tó jẹ́ dandan: Wo ìdí mẹ́ta tí àwọn kan ṣe nífẹ̀ síi àti ìdí mẹ́ta tí àwọn ẹlòmíì kò ṣe gbà á
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tí wọ́n fẹ̀sùn ikú Demilade, ọmọ ọdún méje tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú 'cooler' lẹ́yìn tó dàwátì ní Ado-Ekiti
- Ìjọba ti iléẹ̀kọ́ Ojodu pa, Ó ní àlàyé ohun tó ṣókùnkùn nípa ìjàmbà tírélà tó pa akẹ̀kọ̀ọ́ níbẹ̀ ńbọ̀ láipẹ̀
- Ẹnikẹ́ni kò ní lè yọjú síbi ayẹyẹ kankan l'Eko láì fi ẹ̀rí hàn pé ó ti gbabẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19- Sanwo-Olu
- Àwọn agbébọn dáná sun èrò ọkọ̀ 42 láàyè ní ìpínlẹ̀ Sokoto
O ni " Lati nnkan bii ọjọ diẹ sẹyin lawọn araalu kaakiri Naijiria ti n ke gbajre lori iku Sylvester Oromoni to jẹ akẹkọọ Dowen College niluu Eko."
"Mo pin ninu ibinu yin si iṣẹlẹ yii mo si pin ninu ibanujẹ yi lori ikọ ọmọde ọhun."
"Lorukọ mi ati ẹbi mi ati ijọba apapọ, a ba idile Oromoni kẹdun iku ọmọ wọn, a tun ba ijọba ipinlẹ Eko naa kẹdun pẹlu."
"Mo wa n fi akoko yii da yin loju pe a o ṣe iwadii kikun lori iṣẹlẹ yii, gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ yoo jẹ iya to tọ labẹ ofin."
Lẹyin naa ni Aarẹ ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lati mọ ọkunkundun ọrọ naa ki idajọ ododo le waye lai fi ti ẹni ti ọrọ naa kan ṣe.
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ Dowen College naa ti fi atẹjade mii sita ori iku Oromoni.
Ninu atẹjade naa ni ti sọ pe awọn n fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati tuṣu de isalẹ ikoko ọrọ ọhun.
Wọn tẹnumọ pe ṣe ni o fi ẹsẹ ṣeṣẹ ko to dubulẹ aisan, eyii to mu ẹmi rẹ lọ.
Wọn fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe awọn ti bẹrẹ iwadii awọn lori ẹsun idunkokomọni ti oloogbe ọhun fi kan awọn aṣaaju rẹ kan nile ẹkọ ọhun, asiko ti awọn n ṣe iwadii abẹle lọwọ ni oloogbe naa dagbere faye.
Lẹyin naa ni wọn ba ẹbi ọmọ naa kẹdun, ti wọn si ṣeleri pe idajọ ododo yoo waye lori iku rẹ.