Kidnapped Baptist Church Members: Àwọn ọmọ ìjọ Emmanuel Baptist Church tí wọ́n jí gbé ní Kaduna ti gba ìtúsílẹ̀

Awọn eeyan bii márùndínláàdọ́rin to jẹ ọmọ ijọ onitẹbọmi ti awọn janduku ji gbe ni ipinlẹ Kaduna ti gba itusilẹ.

Wọn ji awọn eeyan naa gbe lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 yii lẹyin ti awọn janduku ọhun ya bo ile ijọsin wọn, Emmanuel Baptist Chuch, to wa ni Kakau Daji, ni jọba ibilẹ Chikun.

Ọjọ diẹ ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe ni awọn janduku naa pa meji lara wọn.

Lọjọ Abamẹta ni awọn eeyan ọhun, ti ọmọde atawọn obinrin wa lara wọn, gba itusilẹ, ti wọn si ko wọn lọ si ijọ Albarkar Baptist Church nibi ti wọn pade awọn mọlẹbi wọn.

Ọkan lara awọn mọlẹbi awọn eeyan naa sọ fun awọn akọroyin pe awọn san owo itusilẹ ki awọn eeyan naa to gab itusilẹ.

Ẹwẹ, kọmiṣọna eto abo abẹle ipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ni awọn ọmọ ogun ti fa awọn eeyan ọhun le ijọba lọwọ ipinlẹ naa lọwọ lọna ati mu ko rọrun fun wọn lati pada sile wọn.

O fi kun pe wọn ti kọkọ ko awọn eeyan naa lọ si ile iwosan fun itọju to peye.

Amọ Aruwan sọ pe oun ko le sọ boya awọn ajinigbe gba owo itusilẹ ki wọn jọwọ awọn eeyan ọhun.