Sotitobire: Bí ìsìn ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ ṣe lọ rèé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tú olùdásílẹ̀ ìjọ náà sílẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn ọmọ ijọ Sotitobire Praising Chapel fi n yin Ọlọrun ninu ijọ wọn to wa lagbegbe Oshile niluu Akure laarọ ọjọ Isinimi.

Eyii lo n waye lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun oludasilẹ ijọ naa, pasitọ Alfah Babatunde nu.

Tìlù tìfọn ló bá dé láàrọ̀ òní nínú ìjọ Sotitobire lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tú olùdásílẹ̀ ìjọ náà sílẹ̀

Adajọ naa ni pasitọ ọhunn ko mọ nnkankan nipa bi ọmọ ọdun kan, Kolawole Godl ṣe di awati ninu ijọ naa.

Ẹsẹ ko gbero ninu ijọ naa, tilu tifọn si ni awọn ọmọ ijọ ọhun fi n yin Ọlọrun fun itusilẹ pasitọ wọn.

Lara awọn to peju sibi isin ọjọ isiinmi akọkọ naa ni iyawo pasitọ ọhun, Bisola Alfah, awọn agbagba ijọ atawọn ogunlọgọ ọmọ ijọ naa.

Awọran bi nnkan ṣe lọ nibẹ ree: