FG to monitor WhatsApp: Ìjọba àpapọ̀ gbé ìgbésẹ láti máa ṣọ́ ojú òpó WhatsApp, SERAP yarí

Ajọ ajafẹtọọmọniyan, SERAP tun ti gbe Aarẹ Muhammadu Buhari lọ sile ẹjọ lẹẹkan sii.

SERAP n fẹ ki ile ẹjọ bẹgidina igbesẹ ijọba Buhari lati maa ṣọ oju opo ikansiraẹni WhatsApp awọn ọmọ Naijiria.

Ipẹjọ yii n waye lẹyin afinkun eto iṣuna kan ti ijọba fọwọsi loṣu Keje, eyii to ya ₦4.87b sọtọ fun ijọba apapọ lati maa bojuto oju opo WhatsApp awọn ọmọ Naijiria.

Abadofin naa yoo fun ijọba apapo laaye lati ṣọ awọn atẹjiṣẹ, to fi mọ awọn ipe ori fidio awọn araalu lori ikanni WhatApp.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ Facebook to ni oju WhatsApp ti ṣe awọn eto kan pẹlu imọ ẹrọ, eyii to mu ko nira lati mọ ohun ti awọn onibara wọn fi n ṣọwọ si awọn ẹlomiran lori ikanni naa.

Ṣugbọn ninu iwe ẹjọ ti SERAP pe niwaju ile ẹjọ giga kan niluu Abuja, wọn ni awọn n fẹ ki ile ẹjọ ọhun fofin de Buhari lati ma le lagbara lati maa ṣayẹwo atẹjiṣẹ awọn araalu lori ikanni WhatsApp.

Gẹgẹ bii ohun ti SERAP sọ, ṣiṣamojuto ohun ti awọn araalu n ṣe lori WhatApp jẹ titẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ, eyii to lodi si ofin.

SERAP ni "Ojuṣe ijọba Buhari ni lati daabo bo ẹtọ awọn ọmọ Naijiria, ṣugbọn ijọba yii kan naa lo fẹ maa tẹ ẹtọn kan naa loju mọlẹ nipa yiyọ oju si igbe aye ikọkọ wọn."

Lara awọn ti SERAP tun pe lẹjọ ni minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami ati minisita fun eto iṣuna, Zainab Ahmed.

Agbẹjọro SERAP, Kolawole Oluwadare sọ pe abala kẹtadinlogoji ofin orile¬̣-ede Naijiria fi aye gba ara ilu si ẹtọ lati gbe igba aye wọn lai si pe ẹlomiran n tojubọ bi wọn ṣe n gbe aye naa si.

O ni awọn ko ni gba ki ijọba apapọ maa tojubọ bi awọn araalu ṣe n gbe igbeaye wọn si.

Wayi o, ile ẹjọ giga naa ko tii sọ ọjọ ti igbẹjọ ọhun yoo bẹrẹ.