You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
MTN Nigeria: MTN CEO fún àwọn oníbárà wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ gbà mábínú lẹ́yìn tí ẹ̀rọ wọn kọṣẹ́
Ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ, MTN, ti sọrọ soke lori fidio kan to gba ori ayejara kan nibi ti ọga agba ileeṣẹ naa ti rawọ ẹbẹ si awọn onibara wọn ni Naijiria lati fi iye denu lẹyin ti wọn ja awọn eeyan naa kulẹ lọjọ kẹsan an oṣu Kẹwaa.
Eyii waye lẹyin ti awọn eeyan bẹrẹ si n fi iṣẹ ranṣẹ si awọn mọlẹbi wọn pe ayederu ni atẹjiṣẹ ti MTN fi ranṣẹ si wọn ṣaaju, eyii to wa lati ọdọ "MTNCEO KARL."
Atẹjiṣẹ lati ọwọ MTNCEO KARL ti awọn eeyan gba ṣaaju yii sọ pe ki awọn onibara wọn lọ wo fidio kan lọfẹ, eyi to sọrọ nipa bi MTN ṣe rawọ ẹbẹ si awọn eeyan naa.
Lẹyin ti ọpọ eeyan gba atẹjiṣẹ fidio ọfẹ lati ọdọ MTNCEO KARL yii, wọn bẹrẹ si n ranṣẹ si awọn eeyan wọn lati ma ṣe ṣi fidio naa nitori o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn karanbani kan lo n fi atẹjiṣẹ naa ranṣẹ si wọn.
Ẹwẹ, MTN ti wa sọ pe awọn gan lo fi atẹjisẹ ọhun sọwọ si awọn onibara wọn, kii ṣe awọn alọkolohunkigbe ori ayelujara.
MTN ni ootọ ni fidio naa, ati pe iṣẹ lati ọdọ ọga agba ileeṣẹ naa lo wa nibẹ nibi ti sọ pe ki awọn onibara wọn ni Naijiria jeburẹ lẹyin ti wọn ja awọn eeyan naa kulẹ lọjọ kẹsan an oṣu Kewaa.
- Ọ̀kan lẹ́ẹ fọwọ́ mú o, nínú ká jẹ gbèsè tàbí ká fi kún owó orí tẹ́ẹ̀ ń san - Fashola
- Ọwọ́ ti tẹ ọlọ́pàá mẹ́ta tó gba N25000 lọ́wọ́ aráàlú lójú pópó tí wọ́n tún fọ́ wọn létí
- Gómìnà Kwara ti pada sọ̀rọ̀ lóríi aáwọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Lai Mohammed, ǹkan ki síbẹ̀
- Òkóbó ni mí àmọ́ ìyàwó mi gbà láti fẹ́ mi lẹ́yìn tí mo sọ fun un - Pásítọ̀ Olumide Oni
- Ìdí rèé tí Oluwo ìlú Ìwo kò fi tíì gbé ìyàwó míìràn gẹ́gẹ́ bí Olórí láàfin
- Wo bí Nkechi Blessing ṣe dákú rọngbọndan níbí ìsìnkú ìyá rẹ̀ l'Eko
Nigba ti BBC Yoruba ṣabẹwo soju opo MTN, fidio naa wa nibẹ, eyii to n ṣafihan pe, ni tootọ, MTN lo fi atẹjiṣẹ ti awọn eeyan n pe ni ayederu sita ranṣẹ.
Ki lo wa ninu fidio naa?
Ọga agba MTN, Karl Toriola sọ ninu fidio naa pe awọn onibara wọn ma binu bi awọn ṣe ja wọn kulẹ lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹwaa.
Torila ni awọn amoju ẹrọ MTN ti ṣe iwadii ohun to fa ti awọn erọ ileeṣẹ naa fi dẹnukọlẹ lọjọ ti a n wi yii.
O ni nnkankan lo ṣẹlẹ ninu ọkan lara awọn ẹrọ naa, eyii to da gbogbo awọn onibara to wa lori ikanni 4G pada si 3G, ṣugbọn ẹrọ naa wa kọṣẹ patapata lẹyin ti ẹmi rẹ ko gbe iye onibara to wa lori 3G ọhun eyii to mu ki gbogbo rẹ kuku dojuru.
Lẹyin naa lo ṣeleri pe MTN yoo da iye owo ati data ti awọn eeyan lo lati aago mejila ọsan si aago meje alẹ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii pada fun wọn gẹgẹ bii ẹbun gba mabinu fun ohun toju wọn ri lasiko ti awọn ẹrọ wọn dẹnukọle.
Ẹwẹ, idi ti awọn eeyan ko ṣe kọkọ gba atẹjiṣẹ naa gbọ ni pe kii ṣe "MTN" ti wọn da mọ tẹlẹ lo fi sọwọ si wọn, ati pe awọn ọmọ Yahoo naa maa n lo irufẹ atẹjiṣẹ bẹẹ lati fi ja ẹrọ ibaraẹnisọrọ eeyan gba, ti wọn a si ja wọn lole.