Tinubu ló ní kí n dákẹ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo mọ èsì tó yẹ kí ń fún Lai Muhammed- Gómìnà Kwara

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gbami nimọran pe ki n ṣe suuru lori ọrọ ti o n daamu ọkan mi nipa Lai Muhammed ṣugbọn mi o le gbagbe abuku to fi kan mi.

Esi ree lati ẹnu Gomina ipinlẹ Kwara Abdulrahaman Abdulrazaq lori aawọ to n fa gbọnmi si omi o to laarin ohun ati Minisita Lai Mohammed.

Igba akọkọ ree ti Gomina yoo sọrọ nipa aawọ yi. Koda igba akọkọ rẹ ree ti yoo tilẹ ba akọroyin sọrọ lati igba to ti de ori alefa ni nkan bi ọdun meji.

Ninu ifọrọwerọ yi, Gomina ni ko si ootọ ninu ọrọ ti Minisista ati awọn kan n sọ pe ohun ko leeyan ninu ẹgbẹ.

Bẹẹ lo ni lati igba toun ti kọ lati ko owo ẹgbẹ fun awọn kan ninu ẹgbẹ ni wọn ti gbogun ti oun.

O ṣe akawe orisirisi ọna ti Minisita Lai Mohammed fi n gba owo lasiko ipolongo ibo lorukọ oun ti ko si fi owo naa jiṣẹ.

''Bẹẹ ni lati igba ti mo kọ lati gbowo kalẹ fun awọn aṣaaju APC Kwara ni wọn ti kẹyin si mi ninu ẹgbẹ.Wọn o kopa ninu ipolongo mi''

''Ile ni wọn joko si ti wọn n wo DSTV titi taa fi pari idibo aarẹ ti wọn si yọju ni idibo Gomina ku ọjọ meloo kan''

Lara ohun ti oju rẹ ri to sọ ninu ifọrọwerọ yi ni bi wọn ko ti ṣe jẹ ki oun wọ inu ọkọ aarẹ gẹgẹ bi oludije ipo Gomina lasiko ti aarẹ wa ṣe ipolongo ni Kwara.

''Ọpẹlọpẹ ọkan lara awọn ẹsọ aarẹ to pada kesi mi lati wa joko sinu ọkọ aarẹ, ẹyin ọkọ akero bọọsi Coaster ni wọn ko ba fimi si''

Abdulrrahaman Abdulrazaq to jẹ Gomina nigba ti iji gbe awọn eekan ẹgbẹ PDP bi Bukola Saraki lọ labẹ asia ''O to gẹ'' sọ pe awọn ko mọ ipa ti Lai Mohammed n ko ni Kwara.

O tẹsiwajupe ko si Minisita kankan ninu awọn mejeeji to wa lati Kwara ti wọn maa n wa sile debi ti awọn yoo ri ipa wọn lara ilu.

''Abuja lawọn mejeeji wa.Wọn kii wa si Kwara.Eko ni Lai maa n lọ.Ibẹ ni ile rẹ wa.Bẹẹ lọrọ ri pẹlu Gbemi Sraki naa. Bi igba pe a ko ni Minisita ni''

O ti to ọjọ mẹta ti aawọ ti wa nilẹ laarin Gomina ati awọn eekan inu ẹgbẹ APC ti pupọ ninu wn si ni ko jẹ ki awọn lẹnu lọrọ ninu ẹgbẹ lati igba to ti de ori oye.

Laipẹ yi ni wọn ṣe idibo abẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara ti awọn igun meji ọtọọtọ si ṣeto idibo wọn.

Ko to di asiko yi, Minisita Lai Mohammed naa ti bẹnu atẹ lu Gomina Abdulrahaman Abdulrazaq ninu fọnran fidio kan nibi to ti ni Gomina ko fi owo kankan kalẹ lasiko ipolongo idibo.

Lai Mohammed sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ to peju sibi ifilọlẹ olu ile ẹgbẹ APC ni Ilorin pe ''amunibini ni Gomina ati pe ojo lo da ẹiyele pọ mọ adiẹ''