Ibrahim Mantu ti dágbére fáyé lẹ́yìn àìsàn ọjọ́ mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, The will Nigeria
Igbakeiji Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, Ibrahim Mantu ti jade laye.
Ẹnikan to sun mọ mọlẹbi oloogbe ọhun, Shehu Nura sọ pe o jade laye lẹyin aisan ranpẹ.
Oloogbe naa di gbajumọ ni Naijria lasiko to wa nile igbimọ aṣofin gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ ile ọhun laarin ọdun 2003 si 2007.
Iroyin ni o ku sile iwosan DIFF to wa niluu Abuja lẹyin ọjọ mẹwaa to ti dubulẹ aisan.
O ni ni oloogbe naa yoo wọ kaa ilẹw sun ni ilana ẹsin Musulumi.
Ọpọ awọn oloṣelu ni Naijiria atawọn mọlẹbi rẹ lo ti bẹrẹ si n sẹdaro iku rẹ.
Lara awọn to n ṣedaro rẹ ni Abubakar Bukola Saraki to gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.
Taa ni Ibrahim Mantu?
Gbajugbaja oloṣelu ti ẹnu kii sìn lara rẹ ni Ibrahim Mantu nigba aye rẹ.
O jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ oludari ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
Ọdun 1978 lo kọkọ darapọ mọ oṣelu.
Lọdun 1993, o di Oludari Agba fun ikọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu National Republican Covention Presidential Campaign Organisation.
Lọdun 1999, Mantu jawe olubori si ipo sẹnetọ lati ṣoju ipinlẹ Plateau labẹ asia ẹgbẹ PDP.
O si jẹ Igbakeji Aarẹ ile aṣofin Naijiria laarin ọdun 2003 si 2007.












