Benue Killing: Gómìnà Ortom yarí mọ́ Buhari lọ́wọ́ lórí àkọ̀tun ìpànìyàn tó wáyé ní ìpínlẹ̀ rẹ̀

Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Otom ti sọ pe kii ṣe ohun to bojumu ki ijọba apapọ fi ṣikun ofin mu Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho nigba ti awọn ọdaran Fulani n yan fanda laarin ilu.

Otom lo sọ ọrọ naa lasiko to n fesi si awọn ikọlu to n waye ni ipinlẹ rẹ, paapaa ni ijọba ibilẹ oun tikalara rẹ.

Ṣaaju ni awọn ọdaran darandaran kan ti kọkọ ṣekupa eeyan mẹjọ ni ijọba ibilẹ Nzorov ati Uvir, lara awọn ti mọlẹbi gomina Otom wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin ni awọn janduku naa sọ pe irufẹ ikọlu bẹẹ yoo maa tẹsiwaju nipinlẹ ọhun, ayafi ti gomina Samuel otom ba gba awọn Fulani laaye lati maa da ẹran laarin ilu, eyii to ti kọkọ fofin de ṣaaju.

Nigba to n fidi iṣekupani naa mulẹ, alaga ijọba ibilẹ Guma, Caleb Aba sọ pe awọn ọdaran Fulani ọhun pa eeyan mẹrin niluu Mbabai to fi mọ oṣiṣe eto iranlọwọ meji.

O ni "Wọn tun pa awọn mẹta miran ni Nzorov, eyii to jẹ ilu bibi gomina Otom ati ẹlomiran niluu Uvir, ni ijọba ibilẹ Guma.

Lasiko to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, gomina Otom sọ pe akẹkọọ kan to wa ni ipele keji ni fasiti ipinlẹ Benue, BSU, wa lara awọn mẹjọ ti wọn pa ọhun.

O ni "O jẹ ohun ibanujẹ pe awọn janduku naa ni ki wọn sọ fun mi pe ki n gbẹsẹ kuro lori ofin to fofin de dida maluu laarin ilu, bi bẹẹ kọ, awọn yoo tẹsiwaju lati fi ẹmi ṣofo."

"Awọn ohun ti a n sọ fun ajọ agbaye niyẹn pe ki wọn gba wa silẹ lọwọ awọn ara 'bi."

Otom tẹsiwaju pe "Mo gbọ ti ẹnikan sọ pe awọn janduku yii da bi ẹmi airi ti ko ṣe e mu."

"Wọn le mu Nnanmdi Kanu, bẹẹ naa ni wọn le ṣo Sunday Igboho di ẹni to n ṣa kiri ṣugbọn o ṣoro fun wọn lati mu awọn ọdaran darandaran."

Otom sọ pe awọn janduku kan ti sọrọ ri lori ayelujara pe ijọba lo n ran awọn niṣẹ ṣugbọn awọn eeyan kan n sọ pe wọn da bi ẹmi airi.

Gomina naa pari ọrọ rẹ pe ọwọ Aarẹ Buhari ni gbogbo rẹ wa nitori ọjọ to ba fẹ ki ifẹmiṣofo naa wa si opin ni awọn iṣẹlẹ ọhun yoo dopin.