NDLEA mú ìyá ẹni ọdún 80 àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú onírúurú oògùn olóró l'Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iya ẹni ọgọrin ọdun kan, ọmọ-ọmọ rẹ to jẹ ẹni ọmọ mejidinlogun atawọn eyan miran ti ko si gbaga ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, lori ẹsun pe n wọn ta oogun oloro.

Lara awọn egboogi oloro ti NDLEA ka mọ wọn lọwọ ni kokeni, heroin, methamphetamine, tramadol, swinol, colorado ati skuchies.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi fi lede, o ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lẹyin oniruru ọfintoto ti wọn ṣe, ati lẹyin ti awọn eeyan ilu kan ta awọn lolobo.

O fi kun pe iwọn egboogi oloro ti wọn ka mọ awọn afurasi naa lọwọ le ni kilo méjìléláàdọ́wàá (192kg).

Ọwọ tẹ mama agba to wa lara awọn afurasi ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Funmilayo Adebayo ni nnkan bii aago mẹfa abọ aarọ lagbegbe Adeyemi, to wa ni ijọba ibilẹ ila oorun Akure.

Lọjọ kan naa ni wọn fi ṣikun ofi mu afurasi miran ti orukọ rẹ n jẹ Tessy Mathew nigab ti wọ kọlu ile irtura Rate to wa niluu Akure kan naa.

Lẹyin naa ni awọn ọtẹlẹmuyẹ NDLEA tun mu afurasi miran, Blessing Adesida, ni agbegbe Oshinlẹ to wa ni ijọba ibilẹ Guusu Akure.

Nigba ti wọn n fi ọrọ wa iya agba ati ọmọ-ọmọ rẹ naa wo, awọn mejeji sọ pe awọn ko mọ pe òwò oogun oloro ti wọn n ṣe ko ba ofin mu.

Bakan naa ni wọn ni awọn ko mọ pe oogun naa le ba aye awọn eeyan jẹ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni awọn mọ pe wọn ko si gbaga ọlọpaa nitori awọn oogun oloro naa, wọn gba awọn araalu nimọra lati ma tọwọ bọ irufẹ owo bẹẹ.

Ẹwẹ, adari ajọ NDLEA, ọgagun Mohamed Buba Marwa ti ke si ọga agba ajọ naa nipinlẹ Ondo lati ṣawari awọn afurasi to ku ti wọn ti na papa bora.