You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Opeyemi Ayeola ní àṣìlò ògùn ibà ku díẹ̀ kó rán òun lọ sọ́run alákeji láìpé ọjọ́
Se wọn ni iku ti yoo ba pa ni, to ba ṣi ni ni fila o yẹ ka dupẹ.
Gbajumọ oṣere, Ọpẹyẹmi Ayeọla ti ke si gbogbo awọn ololufẹ rẹ ki wọn ba oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu bi ori ṣe ko oun yọ lọwọ iku.
Ọpẹyẹmi Ayeọla ṣalaye lori ikanni ayelujara rẹ pe ori lo ko oun yọ lọwọ aṣilo ogun ati pe bi kii ba ṣe Ọlọrun ni, aṣilo ogun ko ba ti ran oun lọ sọrun alakeji.
- Ohun tí Pásítọ̀ Leke Adeboye kọ lẹ́yìn ìròyìn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Dare Adeboye tó jáde láyé
- Nǹkan pàtàkì mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Salawa Abeni bí ó ṣe pé ọgọ́ta ọdún.
- Boko Haram ló jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Greenfield gbé, kìí ṣe àwọn agbébọn ajínigbé lásán- Gumi
- Ẹ̀wọ̀n gbére tàbí ọlọ́dún mẹ́ta, méje, àtàwọn ìjìyà tó ṣééṣe kí Bàbá Ijeṣa jẹ rèé - Ìjọba ìpínlẹ̀ eko
- Ìjínigbé àti ìdigunjalè kò sí ní ìkáwọ́ ìjọba àpapọ̀ - Lai Mohammed
- Àfinra! Amotekun lé àwọn Fulani 137 tó gba inú igbó ìjọba lọ́nà àìtọ́ kúrò l'Ondo
- Mo bẹ Baba Ijesha wò l‘àhámọ́, ẹ́ gbọ́ wirínwirìn ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́ - Yomi Fabiyi
O wa rọ awọn eeyan lati maa ka awọn iwe ikilọ ati atọna to wa lara ogun gbogbo ti wọn ba ra.
O ni eyi fẹrẹ gba ẹmi oun laipẹ yii.
o ṣalaye pe: "ni ọjọ meji sẹyin mo wa ni ibudo yiya sinima kan ni mo ba sọ fawọn akẹgbẹ mi pe o fẹ ṣe bi ẹni tẹ mi diẹ.
Gbogbo wọn ba woye pe boya iba ni, gẹgẹ bi gbogbo wa naa ṣe maa n funrawa ṣapejuwe ohun to n ṣe wa lai ri dokita."
Gbajumọ oṣere naa ni oun lọ si ile itaja ogun kan nigba ti oun pari iṣẹ. O ni oun fẹran Gari gidigidi, loun ba mu Gari ki oun to lo ọwọ akọkọ ogun naa lai ka awọn ọrọ atọna nipa ogun naa to wa lara iwe pelebe ti wọn fi si i lara.
O ni bi oun ṣe lo ọwọ keji ogun naa ni ọjọ Iṣẹgun loun ba gbera kọri si ọna Ikorodu lati ile oun ni ipinlẹ Ogun fun iṣẹ laimọ pe ara ohun to maa n farahan nipa ogun naa ni oyi atawọn nnkan miran koda eeyan lee daku.
"Lai fọrọ gun igba meji ọtọọtọ ni mo daku ni ibi iṣẹ ki wọn to gbe mi de ile iwosan. Koda ni ile iwosan mo tun daku lẹẹkan ki awọn dokita to ri mi."
O ni ileewosan ni wọn ti jẹ koun mọ pe oun ko ni aisan Iba gan an ti oun lo ogun fun, ki oun to tun wa lo ogun naa lai ka iwe atọnisọna to wa lara rẹ.