You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Military Bruitality: Sójà obìnrin lù mí lálù bami nílùú Ibadan
Ọkùnrin kan nílùú Ibadan ló ti ke gbajarè bi obinrin sójà kan ṣe lu òun lálùbami lẹ́yìn tí òun ba ọmọ rẹ̀ wí pé ó fẹ́ jánà mọ́ mótò òun lẹ́nú.
Gẹ́gẹ́ bi ọkùnrin tó ni ìpèníjà ara náà ṣe sọ "Ọmọkunrin kan fẹ́ jána mọ́ móto mi lẹ́nu lójú pópó, "mo sọ̀kalẹ̀ nínú mótò mi láti ba ọmọ náà wi pé kí ó m a ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́"
Ní ọjọ́ keji, ni obinrin sója náà wá dúró dèmí níwájúilé ìwé kan ni òkè ìtùnú Mokola Ibadan, òun pẹ̀lú àwọn obinrin mẹta míràn tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ni da ifọ́tí bòmí. "kò sí ǹkan ti mo le ṣe.
N\igbà tí a tún n pada bọ̀ ni ọ̀san, mó tun ri obìnrin yìí tó wọ asọ sója, ara fun mi pé wọ́n fẹ́ ṣe ǹkan, mo sọ fún ọmọ mi obinrin pe kó mú fóònù kó bẹ̀rẹ̀ sí ni ya àwòrán, Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí ni lù mí gẹ́gẹ́ bi àwọran yìí ṣe fi han
Lásìkò ti BBC Yoruba kan si ọkùnrin náà, ọgbẹ́ni Olumuyiwa Adedeji lówùrọ̀ òní, ó sàlàyé fún BBC pé ilé ìwòsàn ni òun wà lọ́wọ́lọ́wọ́ fún ìtọ́jú ara òun.
Bákan náà lo sàlàyé pé, òun yóò lọ fi ẹjọ sùn ni Bareke Letmack ni agbegbe Mokola gẹ́gẹ́ bi òfin ṣe láásílẹ̀