Coronavirus Update in Nigeria: Èèyan 35 ló ti ru àrùn Coronavirus la ní Naijiria

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Lagos Government

Àkọlé àwòrán, Ni apapọ ẹniyan mejidinlogojilenigba lo ti ni arun Coronavirus ni Naijiria, ti ẹniyan marundinlogoji si ti ri iwosan gba.

Ipinlẹ marun ninu ipinlẹ mẹẹdogun ti wọn ti ni arun Coronavirus lorilẹede Naijiria ni awọn eniyan ti ri iwosan gba.

Ajọ to n risi ipenija ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC loju ikansiraẹni Twitter wọn ni wi pe ẹniyan mejidinlogojilenigba lo ti ni arun naa lati igba to ti bẹrẹ lorilẹẹde Naijiria.

Àkọlé fídíò, Coronavirus symtoms and cure: Seyi Makinde ní Àmàlà gbígbóná

Amọ eniyan marundinlogoji lo ti ri iwosan gba lorilẹede Naijiria, amọ ti ẹniyan marun si ti ku.

Eyi ni akojọpọ awọn ipinlẹ to ti ri iwosan gba ni Naijirialẹyin ti wọn ti ni arun Coronavirus:

Ipinlẹ Eko

babajide sanwo-olu

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu

Gomina ipinlẹ Eko, Babatunde Sanwo-Olu ṣalaye pe wọn ti da awọn meji silẹ ni Ọ̀jọ̀ Aje lẹ̀yin ti ayẹwo fihan pe ara wọ̀n ti da ṣaka.

Ni apapọ ẹniyan mọkanlelọgbọn lo ti ru arun Coronavirus la ni ipinlẹ Eko bayii.

Ipinlẹ Osun

adegboyega oyetola

Oríṣun àwòrán, Adegboyega oyetọla

Eniyan kan ti ri iwosan gba ninu ogun eniyan to ti lugbadi arun naa ni ipinlẹ Osun.

Eyi lo mu ki ipinlẹ naa da ipinlẹ kẹta ti arun naa ti peleke si ni Niajiria.

Ipinlẹ Ogun

dapo abiodun

Oríṣun àwòrán, dapo Abiodun

Ni Ọjọ Kẹsan, Osu Kẹta ni wọn kede ẹni akọkọ to ni arun Coronavirus ni ipinlẹ Ogun.

Nibayii, eniyan kan ninu awọn meji to ni arun Coronavirus ni ipinlẹ naa lo ti ri iwosan gba.

Ipinlẹ Ekiti

kayode fayemi

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government

Ọjọ kejidinlogun, Osu Kẹta ni ijọba ipinlẹ Ekiti kede pe eniyan ti ni arun Coronavirus ni ipinlẹ naa.

Ni bayii, eniyan kan ti ri iwosan gba ni ipinlẹ naa, ninu awọn meji to ti ni ni ipinlẹ naa.

Ipinlẹ Oyo

seyi makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde

Ọjọ kejilelogun, Osu Kẹta ni wọn ni wọn kede ẹni akọkọ to kọkọ ni arun naa ni ipinlẹ Oyo.

Nibayii Gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde to ti ri iwosan jẹ lo jẹ ẹnikẹji to ti ri iwosan gba ni ipinlẹ naa ninu awọn mẹsan to ti ni arun naa.