Coronavirus: èèyàn mẹ́rin kù nínú ilé ìtura àyẹwò Coronavirus to dà wó ni ìlú Quanzhou ni China

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Awọn alaṣẹ ti ni eeyan mẹrin lawọn ri aridaju pe o padanu ẹmi wọn bayi ninu iṣẹlẹ ile itura to dawo ni ilu Quanzhou ni China.

Ile itura yi jẹ eleyi ti ijọba sọ di aaye ayẹwo fawọn ti wọn funrasi pe o ṣeeṣe ki wọn ni aisan Coronavirus.

A gbọ pe wọn ti ri to eeyan mẹtadinlaadọta si aadọrin yọ kuro ninu otẹli titi di asiko ta n ṣe akojọpọ iroyin yi.

Ilú ti wọ́n n pe ni Quanzhou ni ilé itura ti wọ́n ko awọn afurasi Coronavirus yi pamọ si wa.

Ilé alája marun ni otẹli náà.

Awọn fọ́nran to n ṣẹyọ lori ayelujara n sàfihan bi awọn eleto pajawiri sẹ n tú gbogb pàlàpála ile àwọkù náà lati dóòla ẹmi awọn to wà níbẹ̀.

Títí di àasìkò yìí àwọn aláṣẹ ko ti le fi idi ǹkan to fa ìṣẹ̀lẹ̀náà múlẹ, tàbi bóyá ẹnikẹni kú nibẹ̀.

Iṣẹ́lẹ̀ náà wáye ni bíí àgo mọkan la aarọ yìí.

Ọdún 2018 ni wọ́n si otẹli náà, ti ijọba China si fi ibẹ ṣe budo ibi ti wọ́n n ko àwọn afunrasi Coronavirus si.

Ajọ WHO ni ènìyan to le ni ẹgbẹ̀run lọ́na ọgọrun lo ti ni aarun Coronavirus jakejade aye bayii.