You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ile Arugbo: Ẹ̀yin ọmọ Kwara, ẹ seun fún àtilẹ́yìn yin lórí ilé Arugbo
Lẹ́yin gbogbo òun to ṣẹlẹ lóri ọ̀rọ̀ ilé arúgbo ti ijọba ipinlẹ̀ Kwara dà wó lánáà, ọ̀pọ lo n reti ọ̀rọ̀ láti ẹnu ẹni ti ọ̀rọ̀ kan gan.
Sùgbọ́n o, nígbà ti ó di dédé ààgo mẹjọ àbọ̀ ni alẹ́ àná, ni ààrẹ ilé ìgbìmọ asofin nígbà kan rí sẹnatọ Bukola Saraki fọ̀rọ̀ lédé lóri àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ̀ pé gbogbo ǹkan to ti ṣẹlẹ̀ ni ọjọjọ nilé Arugbo, òun dupé lọ́wọ́ àwọn obinrin, Ọkunrin, arugbo àti ọ̀dọ́ ti wọ́n fi ifẹ́ wọ́n han ti wọ́n si dúro ti baba oun to ti di ològbé àti gbogbo ẹbi.
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe lọ́: Mo dupẹ lọ́wọ́ yin fún àtilẹ́yin àti adúroti yín, obinrin àti ọ̀dọ́ wọ́n duro gbọingbọin níwáju ìwà ipá"
" Igbẹ́sẹ̀ yín nígbogbo òru iṣẹ̀lẹ̀ náà fi han gbangba gbàngbà pé ǹkan ti ile Arugbo n ṣe lọ́kan olúkúlùkù wa kò ṣee fọ́wọ́ rọ sẹyin, ati pé kii ṣe ọ̀rọ̀ ilé ti a le foju ri níkan, inú mi sì dùn pé ẹ o jẹ ki ẹnikẹni dunkoko mọ yin, ẹ si dúró lóri ẹsẹ̀ yin."
" Ọjọ òni ko le di ìgbàgbé lọ́kan mi bi ẹ ṣe fi ọ̀kan yin fifẹ han baba mi àti ẹbi rẹ. A si ní ìgbàgbọ́ pé otitọ ni yóò pada lékè laipẹ jọjọ."