Melaye tako èsì ìbò tó gbé Smart Adeyemi wọlé sẹ́nẹ́tọ̀ Ìwọ̀-òòrùn Kogi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Ṣẹneto Dino Melaye ti tako eto atundi idibo si ipo ṣẹnetọ to n ṣoju ẹkùn iwọ- oorun Kogi.

Eyi ko sẹyin bi Ajo Eleto Idibo lorilẹede Naijiria, INEC se sọ wi pe, Smart Adeyemi ti ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle ninu eto atundi idibo to waye ni ẹkun idibo iwọ-ooorun ipinlẹ Kogi.

Dino Melaye lori oju opo ikansiraẹni Twitter ni ohun gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ to n gbẹsun ọrọ to jọmọ eto idibo lati tako esi idibo naa.

Oludije lẹgbẹ oselu PDP naa ni ọpọlọpọ igba ni wọn ti gbero lati pa oun, pẹlu iranwọ awọn to fẹsun kan.

O fikun wi pe magomago ati iwa ipa to ṣẹlẹ lasiko idibo naa ko jẹ ki idibo naa kẹsẹjari, eleyii ti Dino ni pe ko yẹ ki o waye.

Dino Melaye ti dìbò ní àtúndì ìdìbò tó ń lọ lọ́wọ́!

Oludije ni ẹgbẹ oselu PDP ninu atundi idibo sipo sẹnetọ to n soju ẹkun idibo iwọ oorun Kogi ti lo dibo rẹ

Ni owurọ ọjọ Satide ni Melaye fi soju ẹrọ ikansiraẹni Twitter rẹ pe oun ti lọ dibo.

Ajọ Eleto Idibo lorilẹ-ede Naijiiria, INEC ti gbogbo eto lo ti to lati ri i wi pe ko si kudiẹ-kudiẹ ninu atundi idibo sipo sẹnetọ to n soju ẹkùn Ìwọ̀-Òòrùn Kogi.

Eyi ko sẹyin bi oludije fun ẹgbẹ osẹlu PDP se kọkọ yari pe eto atundi idibo naa ko ni waye nitori magomago ati iwa ipa to sẹlẹ, to si fa atundi idibo naa.

Idibo ọjọ kẹrindinlogun, Osu Kọkanla, ọdun 2019 ni wọn fẹ tundi nitori wahala ati rogbodiyan to bẹ silẹ ni ọjọ idibo Àjọ Ìsọ̀kan Yúròòpù àti Amẹ́ríkà bẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìdìbò Kogi àti Bayelsa.

Eleyii to fa a ti wọn wọgile idibo to waye ni agọ idibo mẹtalelaadọta ni ẹkun Iwọ-Oorun Kogi ati mejilelogun ni ẹkun idibo Ajaokuta.

Esi idibo naa fun oludije lẹgbẹ oselu APC, Smart Adeyemi gẹgẹ bi ẹni to n le iwaju ninu eto idibo pẹlu ibo 89,153, nigba ti Melaye ti wọn jọ n figagbaga lati ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo 59,000

Amọ Ajọ INEC gbẹsẹ le eto idibo naa nitori wọn wogile ibo 20,157 ti wọn di ni ibi ti iwa ipa ti waye, ti wọn si ni idibo naa kẹsẹjari.

Saaju idibo loni, ẹgbẹ oselu PDP ti kọ iwe ipẹjọ si ajọ INEC pe ki idibo naa waye, lẹyin ti wọn tako esi idibo ti INEC gbe jade pẹlu ẹsun pe ọpọlọpọ esi idibo naa waye ni awọn agbeegbe ti rogbodiyan ti ṣẹlẹ.

Amọ adari ajọ eleto idibo niipinlẹ naa, Ọjọgbọn James Apam sọ wi pe awọn ti bẹrẹ pinpin awọn ohun eelo idibo, ti wọn si ni awọn wa ni sẹpẹ fun idibo naa.

Ajọ INEC wa rọ awọn eniyan lati jade wa dibo fun ẹni ti wọn fẹ lai si ifoya tabi ipaya.