Rélùwéè Èkó sí Ìbàdàn: tíkẹ́ẹ̀tì ọ̀fẹ́ lẹ ó lò fún oṣù mẹ́rin gbáko- Amaechi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn eeyan Naijiria ti n fi ero ọkan wọn han lẹyin ti ijọba kede irinajo ọfẹ loju opo reluwe laarin ilu Eko si Ibadan.

Minisita feto irinajo ni Naijiria Rotimi Amaechi lo fi ikede yi soju opo Twitter rẹ ti o si ni fun oṣu mẹrin gbako lawọn eeyan yoo fi wọ reluwe ọfẹ.

Kete ti o fi ikede yi sita lawọn eeyan ti n sọ ti ọkan wọn lori ikede yi.

Bi awọn kan ti ṣe n kan sara si ijọba lawọn miran n sọ pe oṣu mẹrin ti pọju lati fi wọ reluwe lọfẹ

Bakannaa lawọn miran n bere bi wọn ti ṣe fẹ ṣeto reluwe ọfẹ ti wọn ko ba ti pari eto to yẹ.

Ikede irinajo ọfẹ lori reluwe ni Naijiria lẹnu igba ti ijọba n gbiyanju lati sọ ka irina yi ji pada kii 'se tuntun.

Ṣaaju ki reluwe laarin ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria si Kaduna gbera sọ,ijọba kede irinajo ọfẹ oloṣumẹta.

Bakanna ni wọn ṣe iru ikede yi nigba ti wọn ṣe ayẹwọ irinajo Eko si Abeokuta to jẹ abala kini oju irin to lọ laarin Eko si Ibadan.

Igbakeji aarẹ Yemi Oṣinbajo ni o ṣe ifilọlẹ irinajo ọfẹ lori reluwe loṣu keji ọdun 2019.