You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akure Church Kidnap: Òbí ọmọ tí wọ́n jígbé àti asọ́nà ṣọ́ọ̀ṣì 14, lọ́ búra nì'dí imọlẹ̀ l'Akure
Idi imọlẹ abalaye ni aafin Ọba Deji ti Akure ni iya ọmọ, baba ọmọ ọdun kan ti wọn jigbe ni ilu Akure ni ipinlẹ Ondo pẹlu awọn aṣona ṣọọṣi mẹrinla ile ijọsin ti wọn ti ji ọmọ gbe. ti lọ bura
Akọroyin BBC to wa ni ibi ti wọn ti bura sọ wi pe owurọ kutukutu Ọjọ Aje ni awọn eniyan lọ si ile Óba Deji lati lọ bura ti wọn ba mọ nipa bi ọmọ naa ṣe sọnu.
O ni igbakeji pasitọ, awọn aṣọna ṣọọṣi lẹyọ kọọkan ati awọn obi ọmọ naa bura ni ọkọọkan wi pe awọn ko mọ owo mọ ẹsẹ si iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo ni wọn tun bura nipa ẹnikẹni to ba mọwọ mẹsẹ si iṣẹlẹ naa pe ki imọlẹ foju ẹ han sita, ko ṣee bi ọṣẹ ṣe n ṣe oju.
Amọ, akọroyin BBC ni ọrọ awọn aṣọna ṣọọṣi naa ti n yatọ si ohun ti wọn kọkọ n sọ tẹlẹ pe eniyan kọ lọ wa gbe ọmọ naa.
Sibẹ wọn ko tii sọrọ ni pato lori bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ati ọna lati wa ọmọ naa ri.
Iya ọmọ ti wọn ji lọ naa sọ fun BBC pe wọn ko ti i ri ọmọ naa titi di bi wọn ṣe n sọrọ, ati wi pe ọmọ ti wọn ri ni Akure pe o sọnu kii ṣe ọmọ oun.
Awọn obi naa wa parọwa si àjọ ọpaa lati mura si iwadii ti wọn n ṣe ki wọn le ri ọmọ naa lasiko.