You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bukola Saraki: Àìbọ̀wọ̀ f'áṣẹ ilé-ẹjọ́ n'ìgbẹ́sẹ̀ EFCC láti gba ilé mi ní Ilorin
Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja ni saa eto ijọba awarawa to kọ ja, Sẹnẹtọ Bukola Saraki ti fẹsun kan ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, EFCC.
Saraki ni pe ajọ naa fẹ gbẹsẹ le ile oun to wa niluu Ilorin.
Ninu atẹjade kan to fi sita l'Ọjọru lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Yusuph Olaniyonu, Saraki ni EFCC lọ sile ẹjọ giga nipinlẹ Eko l'Ọjọru nibi ti wọn ti beere fun aṣẹ lati gbẹsẹ le ile rẹ to wa ni Ilorin.
Loṣu kẹwaa ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ paṣẹ pe ko jọwọ ile rẹ meji to wa lagbagbe Ikoyi niluu Eko.
Ṣugbọn Saraki sọ ninu atẹjade to fi sita pe owo ifẹyinti ati owo ara oun loun fi kọ ile to wa ni ilu Ilorin, ati wi pe lẹyin toun ṣe gomina tan nipinlẹ Kwara loun kọ ile naa.
Sẹnẹtọ Bukola Saraki ni sisọ fun ile ẹjọ pe ko gbẹsẹ le dukia oun ni Ilorin tumọ si idunkooko mọni ati lilo agbara nilo kulo.
Saraki loun ṣetan lati pade ajọ EFCC nile ẹjọ, nitori oun gbagbọ pe nibẹ loun ti le ri idajọ ododo gba.
Bukọla Saraki lo jẹ iyalẹnu pe ajọ EFCC n tako aṣẹ ile ẹjọ giga l'Abuja eleyi to dena ajọ naa lati gba dukia rẹ.
O ni EFCC tun n tako ọrọ adajọ agba patapata ni Naijiria, Ibrahim Tanko Muhammed to sọ pe gbogbo ẹka ijọba gbọdọ bọwọ fun ofin orilẹ-ede Naijiria.
- Owó ìfẹ̀yìntì àwọn Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Zamfara dì àlọrámirámi
- Àṣírí tú! Ẹlẹ́wọ̀n Kirikiri tó ń wọ́ke, olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n ló ṣe onígbọ̀wọ́ fun - EFCC
- Ilé aṣòfin Amẹrika gbọnmú lórí ìtìmọ́lé Sowore, ó ní ìjọba Nàíjíríà tako òmìnira aráàlú
- Ẹ wo ìpínlẹ̀ táwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ àti igbákejì wọn ń gba dúkìá ìfẹ̀yìntì tabua