You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Obìnrin kan gbẹ̀mí ara rẹ̀ lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ fi ṣẹlẹ́yà pé ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú
Obinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan ti gba ẹmi ara rẹ lorilẹ-ede India, latari bi ọkọ rẹ ṣe n fi ṣẹlẹya nitori o jẹ alawọ dudu.
Ajọ ọlọpaa Rajasthan sọ pe baba oloogbe naa fi ẹsun kan ọkọ obinrin ọhun pe, oun lo ṣokunfa bi oloogbe naa ṣe gba ẹmi ara rẹ.
Baba obinrin naa sọ fun awọn ọlọpaa pe, ọkọ obinrin naa maa n fi ṣe ẹlẹya nitori pe aawọ ara rẹ dudu pupọ, idi ree ti obinrin ọhun naa ṣe pa ara rẹ.
- Coronavirus ti di ara wa, kò le è kúrò mọ láéláé - WHO
- Ìdí rèé tí ilẹ̀ Afirika fi gbọdọ̀ kópa nínú dídán abẹ́rẹ́ coronavirus wò
- A ṣetán láti fìyà jẹ ọmọ ogun tí adé ìwà ìbàjẹ́ fídíò náà bá ṣímọ́ lórí- Iléeṣẹ́ ọmọ ogun
- Àwọn ènìyàn ń jìyà lórí ibodè tí wọ́n tì pa yìí - Olókòwò
- Má bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀, wo ìlànà FRSC láti gba nọ́mbà àdáni fún ọkọ̀ rẹ
Awọn ọlọpaa Hindi sọ fun BBC pe, ọkọ obinrin ọhun ko tii ṣorọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede India lo gbagbọ pe obinrin ti aawọ ara rẹ ba pupa tabi to funfun dara ju alawọ dudu lọ.
Iṣẹlẹ yii kọ ni igba akọkọ ti obinrin India yoo gba ẹmi ara rẹ nitori ifiniṣẹsin ati idẹyẹsi to jọ mọ aawọ dudu lorilẹ-ede India.
Gẹgẹ bi ọrọ ti ọlọpaa sọ, obinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan pa ara rẹ lọdun 2014 lẹyin ti ọkọ rẹ fi ṣẹlẹya lataari pe o dudu pupọ.
Bẹẹ naa ni lọdun 2018, ọmọ ọdun mẹrinla kan gba ẹmi ara rẹ, lẹyin ti wọn ni awọn akẹgbẹ rẹ nile iwe fi ṣẹ yẹyẹ, ti wọn si pe e ni oburẹwa, nitori pe o jẹ eeyan dudu.