Coronavirus in Africa: WHO ní ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yóò ṣèrànwọ́ láti pinwọ́ àrùn náà

Adari ajọ to n risi eto ilera lagbaye, WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus ti sọ pe, o ṣeeṣe ki opin de ba kuru-kẹrẹ arun Coronavirus laarin ọdun meji si asiko yii.

Ghebreyesus sọrọ yii nilu Geneva, nibi to ti ni aarin ọdun meji pere ni ajakalẹ arun "Spanish flu" fi ja, ko to kasẹ nilẹ lọdun 1918.

Ṣugbọn o fikun pe, imọ ijinlẹ ti gbinlẹ ju ti ọdun 1918 lọ, nitori naa, o ṣeeṣe ki Coronavirus kogba wọle ki ọdun meji to pe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Arun naa ni anfani lati maa fẹ loju si bi awọn eeyan ṣe n fara kanra, ṣugbọn a ni imọ ijinlẹ to dantọ lati koju rẹ."

Ko din ni aadọta miliọnu eeyan to gbẹmi mi nitori arun Spanish to waye ọdun 1918.

Nigba to n fesi si pe awọn kọlọrọsi ẹda kan n fi arun naa kowo sapo ara wọn, paapaa nipa awọn irinṣẹ idaabo ara ẹni, Ghebreyesus ni ohun to buru gba ni.

O ni iwa ọdaran ni ki eeyan maa lo ajakalẹ arun bii Covid-19 lati sọ ara rẹ di ọlọla, ko si bojumu.

Ghebreyesus ṣalaye pe "Ni temi o, iwa ipaniyan ni ki eeyan maa ṣe jibiti lori irinṣẹ idabo bo ara ẹni, nitori ti awọn oṣiṣẹ eto ile ilera ko ba ni awọn irinṣẹ naa, a n fi ẹmi wọn ati awọn ti wọn n tọju sinu ewu ni."

Lati igba ti arun naa ti ṣẹyọ ni ilu Wuhan lorilẹ-ede China lopin ọdun 2019, miliọnu mejilelogun eeyan lo ti fara kasa arun ọhun kaakiri agbaye, ti eeyan ẹgbẹrun lona ẹgbẹrin si ti ku.

Ilẹ Amẹrika ni arun naa tri ṣọṣẹ julọ, lẹyin rẹ ni Brazil ati India.

Ẹ ṣí ilé ìwé padà ní Áfíríkà torí ọjọ́ iwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yín - WHO, UNICEF

Ẹ ṣi awọn ileewe yin pada ni kopẹ kọpẹ, ajọ eleto ilera lagbaye, WHO lo rọ awọn orilẹede ilẹ Afirika bẹẹ

Ajọ WHO ni gbigbe ileewe tipa siwaju sii nitori coronavirus yoo ṣakoba fawọn akẹkọọ.

WHO rọ awọn olori orilẹede nilẹ Adulawọ lati ri pe eto to mọyan lori wa nilẹ, lori ilana ati idena itankalẹ arun Coronavirus, tawọn akẹkọọ yoo tẹle ti wọn ba wọle pada.

Igbimọ ajọ iṣokan agbaye to n ri si ọrọ awọn ọmọde, UNICEF ati WHO sọ pe, diduro sile awọn akẹkọọ ti jẹ ki ọpọ akẹkọọbinrin gboyun, bakan naa lo ti fi ebi pa awọn akẹkọọ.

Wọn ni ai lọ si ileewe tun ti jẹ ki ọpọ awọn akẹkọọ maa ṣe kongẹ iwa ipa lawujọ.

Ibi isadi ni ileewe jẹ fawọn akẹkọọ nilẹ Afirika, alakoso ẹlẹkunjẹkun ajọ WHO, Matshidiso Moeti lo sọ bẹẹ.

Moeti ni ''a ko le titori pe a n gbogun ti itankalẹ aarun coronavirus ki a padanu ọjọ iwaju wa pẹlu awọn akẹkọọ.''

Iwadii ti ajọ WHO ati UNICEF ṣe fihan pe orilẹede Afirika mẹfa pere lo ti ṣi gbogbo ileewe wọn pada lẹyin ti wọn ti gbe tipa nitori ajakalẹ aarun covid-19.

Awọn orilẹede Afirika kan to ṣi ileewe wọn gbe tipa pada lẹyin ti awọn to n ko aarun coronavirus tun n pọ si.

Awọn orilẹede mii nilẹ Adulawọ ṣi ileewe pada fawọn akẹkọọ to wa ni ipele aṣekagba nikan ki wọn le lanfaani lati ṣe idanwo aṣejade wọn.

Orilẹede Kenya ni tiẹ ti fagile saa eto ẹkọ ọdun 2020 yii.

Ìdí rèé tí ilẹ̀ Afirika fi gbọdọ̀ kópa nínú dídán abẹ́rẹ́ coronavirus wò

Ọpọ iroyin to mu ibẹru dani lo ti jade lori didan abẹrẹ aarun coronavirus wo lara awọn ọmọ ilẹ Adulawọ.

Amọ, awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe o ṣe pataki fawọn ọmọ ilẹ Afirika naa lati kopa ninu didan abẹrẹ naa wo.

Wọn ni aifẹ kopa ninu eto ati dan abẹrẹ covid-19 wo le dena ati ri abẹrẹ ti yoo kapa aarun ọhun lagbaaye.

Loṣu kẹta to lọ ni Ọgbẹni Tedros Adhanom Ghebreyesus to jẹ oludari ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO sọ pe gbogbo agbaye gbọdọ fọwọsowọpọ lori ati wa oogun covid-19.

Ajọ WHO ni lai tii ri oogun coronavirus, abẹrẹ yoo ṣe iranwọ fun adinku itankalẹ aarun naa.

Wọn ti bẹrẹ si ni dan abẹrẹ kan wo lori covid-19 lorilẹede South Africa nigba ti omiiran yoo bẹrẹ ni Kenya lẹyin iyọnda ijọba.

Bawo ni wọn ṣe n san gbà-má-bínú fún ẹni ti wọn bá fi dán abẹrẹ tàbí oògùn wò lára rẹ?

Ileeṣẹ Pfizer dan oogun kan wo lara awọn eeyan ni ipinlẹ Kano ni ariwa Naijiria lọdun 1996.

Eyi lo di ọrọ ileejọ ni eyi ti ileeṣẹ naa ni lati san owo gọbọi gẹgẹ bii owo gba mabinu fawọn eeyan

Omode mọkanla lo ṣalaisi nigba ti awọn miran di abirun lẹyin ti wọn lo oogun antibiotics awogba arun naa tan.

Eyi lo bi ọrọ ki ẹ kọkọ maa gba aṣẹ lọwọ obi ọmọde ki ẹ to fi abẹrẹ tabi oogun kankan dan ara wọn wo.

Ni Uganda ni ogun ọdun sẹyin ni oluṣe iwadii Catherine Kyoubutungi ni o di dandan lati ṣafihan gbogbo igbesẹ inu abẹrẹ tabi oogun ti eeyan ba fẹ dan iṣẹ rẹ wo ki ohun gbogbo si wa letoleto bi o ti yẹ.

Dokita Kyobutungi to jẹ adari ajọ African Population and Research Center (APHCR) sọ fun BBC pe o di dandan ki ẹnikẹni to ba fẹ dan abẹrẹ tabi oogun kankan wo wa ọna ilepa ilera to peye fun irufẹ ẹni to ba fẹ lo

Ati pe igbesẹ loriṣirisi lo ti wa ti wọn gbọdọ tẹle ki wọn to le dan abẹrẹ tabi oogun naa wo lara enikeni nilẹ Adulawọ

Ọpọ ọdun nilẹ Afrika ti ko si owo iranwọ to tó lati ṣe iṣẹ iwadii

Airi owo to too na lati fi ṣe awọn iṣẹ iwadii ninu eto ilera jẹ ọkan lara awọn nkan to n mu iṣoro ba eto ilera Afirka.

Lọdun 2001 ni awọn adari ilẹ adulawọ seleri lati maa mu ida meẹdogun ninu ọgọrun un ninu owo isuna wọn lọdọọdun wa fun iwadii nni eyi ti won ko muṣẹ.

Orilẹ-ede marun un pere lo mu u ṣẹ ninu orilẹ-ede ilẹ Adulawọ.

Afrika ni awọn ọlopolọ pipe ọmọ to ti lami laaka ninu iwadii sayensi ṣugbọn orilẹ imiran ni wọn ti lọ n ṣiṣẹ sin nitori ko si owo fun iṣẹ iwadii nilẹ Afirka. To

Awọn to duro lati ṣe iwadii ni Afrika ko ni oluranlọwọ ni eyi ti ko jẹ ki wọn le maa ṣe ayẹwo pupọ lori iwadii.