Lagos-Ibadan Train: Iléeṣẹ́ Rélùwéè ní ìgbà 16 ní àwọn ọkọ̀ ojú irin náà yóò máa rìn lójúmọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Igba ọtun ati eto idẹrun ti de fun awọn arinrin ajo lati ilu Eko si Ibadan, pẹlu ọkọ oju irin reluwe ti yoo bẹrẹ isẹ losu to n bọ.

Atẹjade kan ti ileesẹ Reluwe nilẹ wa fisita loju opo Twitter rẹ lọjọ Ẹti kede pe ọkọ reluwe mẹrindinlogun lo ti de bayii.

Ileesẹ reluwe ilẹ wa ni awọn ọkọ reluwe naa, ti yoo maa na Eko si Ibadan, ni yoo maa rin ni igba mẹrindinlogun lojoojumọ.

Atẹjade naa fikun pe osu Kẹsan to n bọ ni wọn yoo si eto irinna reluwe lati ilu Eko si Ibadan, ti ara yoo si tu awọn arinrinajo to fẹ lọ silu Ibadan lati Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni eto irinna oju irin yoo tun bẹrẹ lati ilu Itakpe lọ si Warri de Ore, laipẹ laijinna si ni wsn yoo si eto naa.