Lagos train accident: Ọkọ̀ ojú irin pa ènìyàn mẹ́rin ní Eko

Raluwee

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sojú ní wí pé kẹ̀kẹ́ márúwá náà ń tiraka láti gba ojú irin, eléyìí tó jásí pàpo.

Ọjọ buruku esu gbomi mu ni aarọ Ọjọ Isẹgun ni ipinlẹ Eko lẹyin ti ọkọ oju irin kan pa eniyan mẹrin to wa ninu kẹkẹ maruwa.

Agbegbe Iju Ishaga ni ipinlẹ Eko ni isẹlẹ naa ti waye ni nkan bii aago meje ku isẹju mẹẹdogun owurọ.

Àkọlé fídíò, Ìbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà

Awọn ti isẹlẹ naa ṣoju wọn ni kẹkẹ maruwa to ko awọn eniyan mẹrin to padanu ẹmi wọn naa n tiraka lati kọja loju irin ni ọkọ oju irin se ijamba fun wọn.