Iléejọ́ Cameroon: Wọ́n Jẹ̀bi ẹ̀sùn ìṣelòdì sí ìjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileẹjo ti ran awọn ajijangbara meje lọ sẹwọn fún ọdun mẹwaa si mẹẹdogun lori ẹ̀sùn iṣelodi si ijọba ati idunkooko-mọ-ni.
Ile ẹjọ naa ni awọn ajijangbara to n ja fun ominira agbegbe to n sọ ede Gẹẹsi nilẹ Cameroon, ko tẹlẹ ofin ilẹ naa.


Ninu awọn ajijangbara ti wọn n ja fun ominira agbegbe Anglophone nilẹ Camaroon, naa ni olori wọn to tun jẹ akọroyin ni agbegbe Mancho Bibixy.
Awọn akọroyin ni igbohunsafẹfẹ Mancho Bibixy nii se pẹlu ijajagbara to n waye ni ẹkun ariwa-iwọ oorun ilu Bamenda.
Ariwa-iwọ oorun ati Guusu-iwọ oorun ẹkun naa ni agbegbe meji ti wọn ti n sọ ede Gẹẹsi lorilẹ-ede naa.









