Fayoṣe: Ó pé mi kí ń jẹ owó osù ju kí ń lé òsìsẹ́ lọ

Gomina Ayodele Fayose pẹlu awọn asaaju ẹgbẹ osisẹ

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/LERE OLAYINKA

Àkọlé àwòrán, Fayose ni kawọn osisẹ bi ijọba apapọ ohun ti wọn n fi owo se
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gómìnà Ayodele Fayose ti ìpínlè Èkìtì ni lati jẹ oṣiṣẹ lówó oṣù jù kí ìjọba gbà iṣẹ lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìpínlè kan ti ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú APC ń darí ti n ṣe.

Fayoṣe kédè ọrọ náà lójú òpó Twitter re lásìkò ayajọ ọjọ oṣiṣẹ lorílè-èdè Nàìjíríà.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọ wa kesi awọn olórí ẹgbẹ òṣìṣẹ́ láti máṣe kaare nipa bibi ìjọba àpapọ̀ lori ohun ti wọn n fí ọrọ ìlú ṣe.

"Lai se bẹẹ, òpó ìpínlè ní kò ní ríbi ṣe òun tó yẹ"

O ni fún àpẹrẹ, ''dollar méjìlelogójì ní gbedeke iye owó èpo robi ti won lò fún ètò ìṣúná lọdun yi ṣugbọn ni báyìí ti owo èpo tí di aadọrin dollar, nse ni won tun kọ̀ láti sàn gbogbo owo to wole sí akoto apapo ti eyi si lòdì sí àṣẹ ilé ẹjọ to ga julo lorílèèdè yìí .''

Fayoṣe tun dupe lówó àwọn oṣiṣẹ fún àtìlẹ́yìn wọn ati wí pé, bi kìí bá ṣe tí wọn, òun ko ba ti jáwé olúborí nínú ìdìbò to gbe oun padà sípò.