You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
International Champions Cup: Kane fi góòlù àràmọ̀ndà kọ ojú Ronaldo s'óòrùn alẹ́
Ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, Harry Kane gba goolu aramọnda sawọn Juventus ninu idije International Champions Cup ti wọn fi n gbaradi fun saa bọọlu to n bọ lorilẹede Singapore lọjọ Aiku.
Eric Lamela lo kọkọ gbayo wọ le fun ikọ Tottenham ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun ki Gonzalo Higuain to d'ayo naa pada.
Gbajugbaja agbabọọlu Juventus, Cristiano Ronaldo fọba lee pẹlu goolu keji fun Juventus nigba ti ere bọọlu ọhun pe wakati kan geere.
Ṣugbọn agbabọọlu iwaju fun Tottenham sọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun di ọmi alayo mejimeji(2-2) lẹyin to gba bọọlu mii sawọn ni iṣẹju marun din laadọrin.
Ikọ agbabọọlu mejeeji gbiyanju lati bori ninu ifẹsẹwọnsẹ yii titi ṣugbọn o dabi ẹni pe ko si ọna abayọ.
Amọ, Kane to wọ le ni ipele keji ere bọọlu ya ọpọ oluworan lẹnu lẹyin to gba bọọlu lati aarin gbungbun ori papa ti bọọlu si wọ inu awọn lọ.
Eyi lo jẹ ki Tottenham bori Juventus pẹlu ami ayo mẹta si meji ninu ere bọọlu naa.