Premier League: Everton da yẹ̀pẹ̀ sí gaàrí Manchester United

Igbaju igbamu ni kẹrikẹri n ba rode ni Everton fi ṣe fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ninu idije Premier League.

Lẹyin ti Barcelona yọ wọn kuro ni idije UEFA Champions League, Everton fikun ijiya wọn pẹlu ami ayo mẹrin sodo.

Ẹlẹsẹ ayo Richarlison lo kọkọ gba bọọlu sawọn Man U lẹyin iṣẹju mẹtala ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ.

Aaringbungbun Gylfi Sigurdsson lo fọba lee fun Everton lẹyin to gba goolu keji wọ le lati ọna jinjin ti aṣole fun Man U, David De Gea si wo goolu naa wọ le.

Nibayii Manchester United ti wa ni ipo kẹfa bayii ninu idije Premier League, Arsenal wa ni ipo kẹrin nigba ti Chelsea tẹ le wọn ni ipo karun un.

Everton to gbẹyẹ lọwọ Man U ti bọ si ipo keje bayii lẹyin ti wọn gbo ewuro soju Manchester United.