You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
LASEMA: Ènìyàn 3 kú, àwọn tó fara pa ń gba ìtọ́jú
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Eniyan mẹta ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ agbegi ni afara agbegbe Ojuẹlẹgba ni ipinlẹ Eko.
Isẹlẹ naa waye nigba ti igi nla rebọ lati ori ọkọ agbegi to n sọkalẹ lori afara agbegbe Ojuẹlẹgba ni ilu Eko, ti igi naa si wo lu awọn ọkọ tó ń rékọjá lórí afárá náà.
Ajọ to n risi ọro pajawiri ni ipinlẹ Eko, Lasema to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, fi kun un pe eniyan mẹta naa ku loju ẹsẹ, ti ọpọ si farapa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lasema ni awọn to farapa ninu ijamba ọkọ naa ti wa ni ile-iwosan.
Iroyin sọ wi pe, igba akọkọ kọ niyi ti iru ijamba yii yóò sẹlẹ ni afara Ojuẹlẹgba ni ilu Eko.