You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìsẹ̀lẹ̀ Èkó: Àwòrán bí èèyàn mẹ́ta se bá ìjàmbá lọ
Ajọ to n risi ìsẹ̀lẹ̀ pajawiri ni ipinlẹ Eko, Lasema, to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, fi kun un p, eniyan mẹta naa ku loju ẹsẹ, ti ọpọ si farapa.
Ọkọ̀ akérò kan tí igi náà wó lù mọ́lẹ̀ ló rún jégé-jégé.
Èrò kò gbẹsẹ̀ ní ibití ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Kò sí ibi tó kù mọ́ lára ọ̀kọ̀ tí igi wó lù yìí
Àlààfíà ti ń padà sí àdúgbò Ojúẹlẹ́gba, tí àwọn òsìsẹ́ ìjọba sì ti ń tún àyíká ibití ìsẹ̀ll náà ti wáyé se
Kátà-kárà ti bẹ̀rẹ̀ padà ní agbègbè tí ìjàmbá náà ti wáyé.
Gbàgede òkè àti ìsàlẹ̀ ibití ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá náà ti wáyé
Àwòrán ọ̀kọ̀ tó ní ìjàmbá gbẹnu tán ní Ojúẹlẹ́gba.
Haa, irú kín ni èyí ni ọ̀pọ̀ èèyàn n sọ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà.
Ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá tó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́ta lọ nigba ti igi nla rebọ lati ori ọkọ agbegi to n sọkalẹ lori afara Ojuẹlẹgba ni ilu Eko gba ẹ̀nu tán.