Ileesẹ ologun Naijiria: A mu afurasi Boko Haram mẹrin

Ọwọ awọn ologun ti tẹ afurasi kan lara awọn ikọ Boko Haram nileto Kalaa nijọba ibilẹ Hong nipinlẹ Adamawa.

Awọn afurasi naa wa lara awọn tileesẹ ologun fi orukọ wọn sita pe wọn jẹ asiwaju ikọ Boko Haram.

Awọn ologun ni ọwọ tẹ afurasi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Bubayi Isa, to wa lati ileto Panama lagbegbe Gunda nijọba ibilẹ Biu nipinlẹ Borno, lẹyin ti eeyan kan ta wọn lolobo nipa rẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Bakannaa ni wọn tun salaye wipe afurasi ọhun ti jẹwọ ara rẹ pe lootọ loun wa pẹlu ikọ adukukulaja Boko Haram, ti oun si ti kopa ninu ọpọlọpọ awọn ikọlu ti wọn ti gbe se.

Iwadi ileesẹ ọmọogun tun yọju rẹ sita wi pe orukọ afurasi naa, Burayi lo wa ni ipo kẹtadinlogoji ninu akọọlẹ awọn afurasi ti olu ileesẹ ologun lorilẹede Naijiria fi sita saaju asiko yii.

Awọn afurasi miran ti ọwọ awọn ologun tun tẹ ni Muhammad Buba ati Abdullahi Abubakar ti wọn wa lati agbegbe kan naa pẹlu Yakubu Abdullahi to wa lati Sabon Gari Gado nipinlẹ Borno.