You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Champions League: Sevilla f'agba han Man Utd, yọ wọn kuro ninu idije
Ẹgbẹ agbabọọlu Sevilla ti le ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United kuro ninu idije Champions league ti saa yi lẹyin ti wọn f'agba han ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Jose Mourinho ni papa iṣere Old Trafford lọjọ iṣẹgun.
Sevilla gbo ewuro si oju Manchester United pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan ninu ẹsẹ keji idije ikọ komẹsẹoyọọ ipele ẹlẹni mẹrindinlogun (last 16).
Wissam Ben Yedder pari iṣẹ fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti o wa lati orilẹede Spain, lẹyin ti o jẹ ami ayo laarin iṣẹju meji ti o wọle s'ori papa.
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ko ta biọbiọ rara lẹyinkule wọn pẹlu bi Sevilla ti ṣe wọn bi ata tii n ṣ'oju ninu eyi ti Wissam Ben Yedder ti jẹ amni ayo meji lati yọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United kuro ninu awo idije Champions league.
Romelu Lukaku jẹ ami ayo kan ṣoṣo fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ṣugbn ẹpa ko boro mọ.
Ni bayi, ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti ṣe jade kuro ninu idije yii, pẹlu Tottenham, ṣugbọn awọn ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ati Liverpool ntẹsiwaju.
Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea le darapọ mọ wọn bi wọn ba le e lu Barcelona ni ọjọru.
Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: