Iku akẹkọ l'Osogbo: ọkọ ayọkẹlẹ pa ọmọ ileewe girama

Ariwo ẹkun sọ ni ilu osogbo lasiko ti ọkọ ayọkẹlẹ kan pa ọmọde jojolo kan.

Ọkọ ayọkẹlẹ naa pẹlu nọmba idanimọ ọkọ Lagos JJJ243 EF kọlu, ọmọdekunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Samadi Azeez, akẹkọ ileewe girama akọkọ Gbodofon Middle school ni'lu Osogbo.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ni Samadi wa si ọja Ayegbaju lati wa ra ata ni ki iku to ṣe kongẹ rẹ.

"Agbegbe ogo-oluwa ni ọkọ naa ti n sare bọ ki o to lọ kọlu ọmọde naa."

Bi iwadi ileeṣẹ BBC tun ti ṣe fi mulẹ, ọmọ ọkan lara awọn aṣiwaju ẹgbẹ ọlọkọ ero ni ilu Osogbo ni Samadi bẹẹni wọn ni ọmọde kunrin ọhun n gbaradi lati ṣe idanwo aṣekagba ileẹkọ girama akọkọ, JSSCE ki iṣẹlẹ buruku yii to ṣẹlẹ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Ọgbẹni Razak Azeez to jẹ baba ọmọde to di oloogbe naa ni "ẹnu isẹ ni wọn ti pe mi ni ibudokọ ti mo ti n ṣiṣẹ lati wa wo oku ọmọ mi".

O ni wọn gbe oku Samadi si ile igbokusi ti ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun LAUTECHTH to wa nilu Osogbo.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awakọ ayọkẹ yii ko tii fi ara han, ko pẹ pupọ lẹyin iṣẹlẹ buruku yii ti awọn ọdọ kan ti dana sun ọkọ ayọkẹlẹ naa.