Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe, kódà, mo ń tún 'Pumping Machine'- Afusat Adeniyi

Iṣe Ajogunba wo ni ẹ ba lọwọ awọn Obi yin?

Ifọkansin ati itẹpamọṣẹ lo gbe mi de aaye ti mo wa yi- Onimọ ẹrọ Afusat Adeniyi

Arabinrin yii ni akọsẹmọṣẹ to n tun gbogbo ohun eelo ati ẹrọ to n lo kọ́ìlì ṣe.

Afusat salaye bi o ṣe kọṣẹ yii lọdọ baba rẹ to jẹ jorinjorin wẹ́dà ati aburo baba rẹ to jẹ́ eni to n tun ohun eelo to n lo kọili ṣe.

Kini Afusat tun sọ?

Arabinrin Afusat tun parọwa fun awọn Obi ati Alagbatọ lati tubọ kọ ọmọ.

O ni ki wọn je ki wọn kọ iṣẹ ọwọ mọ ti iwe ti wọn n ka.

Bakan naa lo sọrọ nipa irinajo aye rẹ.