Imam Afeez Akinola declares for Presidency: Ànọ́bì gan ló ni òṣèlú, Islam gangan ló ni òṣèlú, báyìí ló ṣe pàṣẹ fún mi

"Laarin ọdun kan gbogbo ohun to ti bajẹ lo maa to, walahi, aṣẹ Ọlọrun ni".

Ọjọ diẹ sẹyin lọsẹ yii ni Alfa Olasupo Akinola naa bọ sita pe oun n kede lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Lori ayelujara, aworan rẹ wa kaakiri to gbe aworan ara rẹ ati ipo to n lọ fun dani.

Olasupo kede erongba rẹ niwaju awọn ọmọ ìjọ rẹ n'ilu Ibadan lọjọ Aiku.

Ọrọ to si gba ori ayelujara kan lọjọ naa ni pe Ọlọrun lo sọ fun oun pe ki oun dide lọ gbe apoti idibo lati di aarẹ.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba gbera lọ si ilu Ibadan nibi ti Alfa yii fi ṣe ibudo lati jẹ ko tan imọlẹ si ọrọ lerefee ti awọn eeyan n ka lori ayelujara.

Nibẹ la ti rii wipe Ọmọwe gaan ni Alfa yii to si tun ni imọ kikun nipa ẹsin Islam ati pe eyi ko fa a kuro ninu oṣelu gẹgẹ bo ṣe n ṣe takuntakun ninu ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC bo ṣe sọ.

"Lati igba ti mo ti pari ile ẹkọ ti mo si darapọ mọ oṣelu, gbogbo awọn adari to ti dide ni mo n tẹle tọkantọkan".

O ni lati ileewe naa ni Ọlọrun ti ni oun fẹ lo oun lati tun orilẹede yii ṣe.

Iha wo ni sin Islam kọ si didarapọ mọ oṣelu

Iha ti ẹsin Islam kọ si òṣelu pọ gidi gan, imọ ti aye ko lee dari oṣelu, eeyan Ọlọhun naa lo le dari orilẹede yii, ti yoo mu aye bintin bayii".

Sheikh ni oun mọ pe gbogbo eeyan lo maa n gbadura ni Naijiria torinaa ki gogbo wọn lọ gbadura si orukọ oun wo boya oun ni ki wọn si gbaruku ti oun.

O fi kun un pe bi oun ba di aarẹ, onikaluku ni yoo maa ṣe ẹsin rẹ lọtọọtọ.