Banji Akintoye: Ọgọ́ta mílíọ́nù ni àwọn ènìyàn ẹ̀yà Yòrùbá ní Nàíjíríà, a tó dá dúró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè

Oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni idibo si ipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Ekiti, nigbati idibo sipo gomina yoo waye ni Osu Keje, ni ipinlẹ Osun.

Adari ikọ to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti ni "ani sẹẹ, ko ni si idibo sipo gomina ni ipinlẹ Osun ati ipinlẹ Ekiti ni ọdun yii".

Akintoye sọ eleyii lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori ipadabọ rẹ si orilẹede Naijiria, lẹyin ti Sunday Igboho ti gba itusilẹ ni orilẹede Republic of Benin.

O ni ikọ Ilana Ọmọ Oodua fẹ fi agbara ofin ati agbara ileẹjọ da idibo duro ni ipinlẹ Osun ati Ekiti, ti o si da awọn loju pe idibo naa ko ni waye.

''Ti wọn ba gba ọna ẹburu ni ileẹjọ kekere, ti wọn si da ẹjọ wa nu. A o gbe wọn lọ si ileẹjọ giga lati rii pe idibo naa ko waye.''

''A pe ijọba lẹjọ nitori pe o ti d'oju ẹ, a ko fẹ ba ẹnikankan ja sugbọn a gbọdọ gba ara wa silẹ, ati lọ si ileẹjọ, mo si mọ pe a o bori nitori ko si ẹni ti ko mọ wipe eru ni iwe ofin ọdun 1999.''

''Awọn ọmọ wa fẹ fi agbara wọn han, awa ni a n bẹ wọn pe ki wọn ma ṣe bẹẹ, ki wọn fi awa baba wọn silẹ ki a yanju ẹ.''

Adari ikọ Ilana Ọmọ Oodua naa ni ipinnu oun ni pe oun fẹ ki ilẹ Yoruba kuro ni Naijiria ṣugbon kii ṣe nitori pe wọn korira awọn ẹya iyoku.

''Ni Naijiria, awa Yoruba to ọgọta miliọnu eniyan, a ki n ṣe ẹya kekere, ko yẹ ki a wa ni abẹ ẹya miran.''

''Ki awọn oyinbo to de ni a ti n se eto ara wa, ti a ti n lọ si Fasiti. Awọn ara Eko ti ṣeto lati da fasiti silẹ lati 1890s, ko yẹ ki iya ki o maa jẹ awọn ọmọ wa titi ti wọn fi n salọ si orilẹede miran.''

''Awọn ọmọ Oodua ti pinnu lati kuro ni Naijiria, iya ko ni jẹ awọn ọdọ wa mọ, a o ko wọn kuro ni ilẹ Naijiria.''

''Itiju ati oṣi lo mu ki awọn ọmọ wa maa sa lọ si oke okun, ko yẹ ki awọn ọmọ wa maa lọ kaakiri lati lọ tun ilẹ ibomi ṣe, ilẹ Yoruba ni Ọlọrun fun wọn lati tun ṣe.''

''Nkan ti a n sọ fun ijọba Naijiria ni wipe ki wọn jẹ ki onikaluku lọ ni tiẹ, a fẹ ilu ti wa, a si gbagbọ pe ẹtọ ti Ọlọrun fun wa ni. Ko si ẹnikẹni to si le gba ẹtọ wa.''

''Ti a ba si ri awọn ẹya miran to fẹ wa gbe ni Ilu wa, a o gba wọn pẹlu ifẹ, wọn yoo si maa ṣiṣẹ , wọn a ma jẹ igbadun nitori a ko ni ija pẹlu ẹnikẹni.''

Banji Akintoye fikun un pe oludije sipo aarẹ lọdun 2023 to tun jẹ gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Eko, Bola Tinubu fẹran Yoruba Nation ati pe ti o ba to asiko, yio mọ nkan ti o le ṣe.''

''Ko si nkan ti Buhari ṣe lati igba to ti di aarẹ ni ilu Naijiria, niṣe lo tun bajẹ si.''

''Bakan naa ni o wa gba awọn ọdọ ni imọran pe ki wọn ma bẹru ẹnikẹni ti o dẹru ba wọn pe wọn ma gba ilẹ wọn.''

'' Bi gbogbo awọn Fulani patapata ni Ọyọ, Ondo tabi Ekiti ba wa, ẹ le wọn pada! awọn ti o wa ni inu igbo, ẹ lo le wọn kuro nibẹ.''