'Owó ọkọ̀ tó ti wọ́n ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ tí wọ́n ti ń san ₦150,000 fún mi lóṣù sílẹ̀'

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Láti ìgbà tí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà, NNPCL ti kéde àlékún lórí owó epo bẹntiróòlù ní àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè ti ń kọminú lórí ìṣòro àti ìpèníjà tí àlékún náà yóò mú bá wọn.

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹta oṣù Kẹsàn-án ni NNPCL kéde àlékún ₦280 sí iye lítà epo, tó sì sọ iye epo di ₦897 láti ₦617 tó jẹ́ tẹ́lẹ̀.

Kò sí àní àní pé àlékún owó náà yóò tún jẹ́ kí owó ọkọ̀ tún gbẹ́nu sókè si. Ní ìlú Abuja, ibi tí wọ́n ń gbé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà (₦500) tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti ń gbé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin naira (₦700) báyìí.

Mi ò lè gbé ìyàwó nítorí ọ̀wọ́n gógó

Nuhu Aminu Nuhu tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ní ìlú Abuja pinnu láti fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ nítorí iye tó ń ná láti fi máa wọkọ̀ lọ sí ibi iṣẹ́ lóṣù.

“Mò ń gbé ní Katampe ní ìlú Abuja, Àpò Resettlement sì ni ibi iṣẹ́ tí mo máa ń lọ ní ojoojúmọ̀ wà. Yàtọ̀ sí owó oúnjẹ, ₦2,500 ni mo máa ń ná láti fi wọkọ̀, owó oṣù mi kò sì ju ₦150,000 lọ.

“Nítorí náà ni mo ṣe fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ láti máa wá nǹkan míì ṣe.

“Ọlọ́run bá mi ṣé pé mi ò tíì gbé ìyàwó, ìdí nìyí tí mi ò sì ṣe fẹ́ gbé ìyàwó lásìkò yìí nítorí à ti bọ́ ẹbí kò rọrùn.”

Ó ṣàlàyé pé òun ń ronú láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ àti wá iṣẹ́ lọ sí ilẹ̀ òkèrè.

Nuhu ni òun gbàgbọ́ pé kò sí orílẹ̀ èdè tí kò máa la ọ̀wọ́n gógó kọjá lásìkò yìí àmọ́ ti Nàìjíríà lágbára púpọ̀ ni.

'Mo fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọkọ̀, mà á ma wá nǹkan ṣe lórí ayélujára'

Ẹlòmíràn tí òun náà jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń kọ́ ilé, Ashraf sọ pé nǹkan kò rọgbọ pàápàá lórí iye tí òun fi ń wo ọkọ̀ ni òun náà ṣe fi iṣẹ́ oṣù tí òun ń sílẹ̀.

Ó ní ₦80,000 ni òun ń gbà lówó oṣù tí òun sì ń gbé ní Apo tí iṣẹ́ òun sì wà ní Mabushi.

Ó sọ pé tí òun bá ń yọ owó ọkọ̀ tí òun ń wọ̀ lójúmọ́ kò ní sí owó kankan tó máa kù nílẹ̀ mọ́ fún òun.

Nígbà tí BBC bèèrè lọ́wọ́ pé kí ni Ashraf yóò máa ṣe báyìí lẹ́yìn tó ti fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló wà lórí ayélujára láì kúrò ní yàrá rẹ̀, ó ní òun yóò wá iṣẹ́ ṣe lórí ayélujára láì ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fi owó wọ ọkọ̀.

Ashraf fi ẹ̀hónú rẹ hàn pé àwọn adarí Nàìjíríà kò mójútó ohun tó yẹ kí wọ́n mójútó, pé wọ́n kàn ń gbà lọ́wọ́ àwọn mẹ̀kúnnù ni.

Kí ni èyí túmọ̀ sí fún Nàìjíríà?

Dókítà Lawal Habib tó jẹ́ olùkọ́ ni ẹ̀ka ìmọ̀ ètò ọrọ̀ ajé ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Kano sọ fún BBC pé ìdúnkokò ńlá ni nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ náà jẹ́ fún Nàìjíríà.

Ó ní kìí ṣe ohun tó bójúmu kí òṣìṣẹ́ má lè ra oúnjẹ tàbí ṣe nǹkan tó yẹ fún ara wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ owó ọkọ̀ àti owó orí nínú owó oṣù wọn.

Dókítà Habib ní tí àwọn òṣìṣẹ́ bá ń fi iṣẹ́ sílẹ̀ le mú àlékún bá àwọn ìwà kò tọ́ ní àwùjọ bíi:

  • Ìwà àjẹbánu
  • Àlékún nínú ìṣẹ́ àti òṣì
  • Ètò ọrọ̀ ajé máa dẹnu kọlẹ̀

Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé náà wá rọ ìjọba láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan yìí láti mú ìgbé ayé àwọn ènìyàn rọrùn;

  • Ṣíṣe àmójútó owó epo
  • Kí ìjọba ṣe ìdádúrò mímú àlékún bá owó orí
  • Wá ọ̀nà láti mú kí owó náírà gbèrú si
  • Kí ìjọba wá ọ̀nà tí wọn yóò máa pèsè láti kó lọ sí ilẹ̀ òkèrè

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ kéréje tí wọ́n nílò láti máa wọkọ̀ lọ sí ibi iṣẹ́ ni wọ́n ń fi iṣẹ́ sílẹ̀.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń pàrọ̀ iṣẹ́ sí èyí tó súnmọ́ wọn tàbí orí ayélujára táwọn mìíràn sì ń fi iṣẹ́ sílẹ̀ láì mọ nǹkan míì láti ṣe.