You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àjọ DSS tu Ajaero olórí àwọn Ọṣìṣẹ́ sílẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n kò fún un ní ìwé ìrìnnà rẹ̀
Iroyin to n jade bayii ni pe àjọ ọtẹlẹmuyẹ Department of State Services (DSS) ti tu olori ẹgbẹ́ oṣiṣẹ, Joe Ajaero silẹ.
Ajaero naa si ti fidi ẹ mulẹ fun Channels pe nkan bii aago mọkanla alẹ ana (ọjọ Aje) ni wọn sọ pe ki oun maa lọ sile.
Ajaero sọ pe o to wakati mẹẹdogun ti wọ fi n fi ọrọ wa oun lénu wo lati igba ti wọn ti mu oun ni aago meje aarọ ninu papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.
Kini Ajaero tun sọ?
Ajaero ṣalaye pe ajọ DSS ko fi iwie irinna oun silẹ fun idi eyi ko si ibi ti oun le rinrin ajo lo nilẹ okeere lasiko yii.
O ni pe yatọ si awọn ajọ DSS, awọn ọlọpaa miran naa tun wa fi ọrọ wa oun lenu wo nibẹ lori iṣẹlẹ iwọde Ebi n pa wa #End Bad Governance to waye loṣu kẹjọ ọdun yii.
Ajaero tun salaye pe awọn agbofinro fi ọrọ wa oun lẹnuwo lori igbesunmmọmi .
Yàtọ̀ sí mímú Ajaero sí àhámọ́, DSS tún kọlu ọ́fíìsì SERAP
Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni wọn tun ti wa loju opo ọpọ iwe iroyin lorilẹede Naijiria lẹyin ti wọn nawọ gan an aarẹ ẹgbẹ oṣiṣe lorilẹede Naijiria, Joe Ajaero.
Mimu Ajaero si ahamọ lo waye lẹyin ọsẹ meji to dahun si ipe ileeṣẹ ọlọpaa lori sise owo ilu mọkumọku ti wọn fi kan.
Ẹwẹ ohun pato ti Ajaero se ti wọn fi mu si ahamọ lo si sokunkun si ọpọlọpọ , ti ajọ DSS ko si ti kede idi ti wọn gbe igbesẹ naa.
Bi iroyin nipa Ajaero se n lọ lọwọ, ni ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ, SERAP, pariwo sita pe ajọ DSS se abẹwo si ileeṣẹ wọn niluu Abuja.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sori ayelujara se ti ṣalaye pe ajọ DSS n bẹrẹ lati ri awọn adari wọn
Lori iṣẹlẹ mejeeji yii , ajọ DSS ko ti sọ ohunkohun nipa rẹ.
Àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ti fọwọ́ òfin mú ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC Joe Ajaero
Iroyin to tẹ wa lọwọ ti sọ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fi ọwọ ofin mu aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero.
Agbenusọ ẹgbẹ NLC, Benson Upah, lo fidi ọrọ mulẹ fun BBC Pidgin.
Ọgbẹni Upah sọ pe Ajaero wa lọna irin ajo rẹ si orilẹede UK nibi to ti n lọ fun ipade ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ni DSS ti nawọ gan an.
Ajọ DSS gbe igbesẹ yii lẹyin ti ileeṣẹ ti fọrọ wa a lẹnu wo tan lori ẹsun wi pe o n ṣagbatẹru igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.
Ninu aworan kan ti NLC gbe sita lori ayelujara, ẹgbẹ oṣisẹ kede sita pe DSS nawọ gan an Joe Ajaero ni paapa ofurufu Nnamdi Azikwe niluu Abuja.
Bakan naa ni wọn kede pe Ajaero ti wa ni ahamọ bayii ni ọfisi NSA.
Ọgbẹni Upah bu ẹnu atẹlu igbesẹ DSS, to si ṣapejuwe rẹ gẹ gẹ bii ti tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ nitori wọn ko fi igba kankan kede pe awọn n kesi Ajaero pe ko yọ oju si wọn.
“Ohun ti ijọba se yii ni ko ba ofin mu rara , ti wọn si gbe gbogbo igbesẹ latin ri pe wọn pa ẹnu awọn eeyan mọ lati ma le sọrọ sita nitori kudiẹkudiẹ to ba eto ọrọ aje eyi to n ni araalu lara pupọ.”
Upah ni gbogbo igbesẹ ni ẹgbẹ naa n gbe lati ri ojutu si iṣẹlẹ naa
Ki lo sẹlẹ saaju?
.Ni oṣu to kọja Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ranṣẹ pe aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, ẹka ti NLC, Joe Ajaero
Ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ni ileeṣẹ ọlọ̀paa ranṣẹ si Ajaero lati yọju si wọn.
Amọ aarẹ ẹgbẹ NLC ọhun sọ pe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, to jẹ Ọjọbọ, ni oun yoo yju.
Lẹyin eyi ni awọn ọmọ ẹgbẹ dunkooko pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi, ti awọn ọlọpaa ba fi mu aarẹ wọn.
Ogunlọgọ awọn oṣiṣẹ ọhun si lo pejọ si olu ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Abuja, lati sẹ atilẹyin fun Ajaero.
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Joe Ajaero ti sọ pe ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan oun ko lẹsẹ nilẹ, ati pe awọn ko le kawọ gbera fun ẹnikẹni lati maa dunkooko mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria.
Joe Ajaero lo sọ eyi ni kete to kuro ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja, nibi to ti lọ dahun awọn ibeere lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Ileṣẹ ọlọpaa Naijiria tun ranṣẹ pe aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, ẹka ti NLC, Joe Ajaero nigba keji.
Wọn ni ki Joe Ajaero yọju si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja l’Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan an, ọdun ti a wa yii.
Ninu lẹta kan ti kọmiṣanna ọlọpaa, Ibitoye Rufus Alajide buwọlu lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, o sọ pe ki Joe Ajaero ati Emmanuel Ugboaja to jẹ akọwe agba fẹgbẹ NLC yọju si wọn lọjọ karun-un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024.