Kí ló fa rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ ní UK? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Lati ọsẹ to kọja ni wahala ti bẹrẹ nilẹ Gẹẹsi lẹyin tawọn afurasi ọdaran kan gun awọn eeyan ariwa guusu England lọbẹ nibi ti ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹta kan ti ku.

Iṣẹlẹ yii ni awọn kan lo lati maa fi ẹhonu wọn han sawọn ti kii ṣe ẹya alawọ funfun.

Iṣọ oru to ti n lọ pẹlu alaafia lo ti fi aaye silẹ fun iwa ikọlu ati iparun.

Iwa ikọlu to dide lara ẹhonu yii la gbọ pe awọn ẹya ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ sii ṣe ikọlu si awọn ti kii ṣe ẹya wọn, to si ti tan kaakiri de awọn ilu bii Hull, Liverpool, Manchester, Blackpool ati Belfast.

Latigba ti ikọlu yii ti bẹrẹ ni awọn alaṣẹ orileede India, Nigeria ati Malaysia ti parọwa si awọn eeyan won ati alakoso ilẹ Gẹẹsi nipa irin ajo.

Olootu ijọba, Keir Starmer ti ṣapejuwe ikọlu ọhun gẹgẹ bi iwa awọn tọọgi, to si ni ko si idi pataki kankan to le fa iru igbesẹ bayii.

Iroyin ofege

Ni kete ti iroyin bi wọn ṣe gun ọmọdebinrin naa pa jade sita, oriṣiriṣi iroyin ẹlẹjẹ lo tan kalẹ nipa idanimọni ẹni to ṣe ikọlu ọhun, to si n kaakiri ori awọn ikanni ayelujara.

Nitori ọjọ ori rẹ, awọn ọlọpaa sọ pe ọmọdebinrin, ẹni ọdun mẹtadinlogun kan ni ọwọ tẹ lori ẹsun naa, ti awọn si ti foju rẹ ba ile-ẹjọ, lojuna lati dawọ iroyin ẹlẹjẹ naa duro.

Ṣugbọn awuyewuye ti awọn eeyan n gbe kaakiri ori ayelujara ni pe ẹlẹsin Musulumi kan to wa sapamọ fun aabo, ẹni to ba ọkọ oju omi wọle siluu naa lo ṣe ikọlu ọhun, ti awọn alẹnulọrọ lori ayelujara si n sọ fawọn eeyan lati ṣe ikọlu.

Ọkan lara awọn alẹnulọrọ naa lori ikani X ni, Stephen Yaxley-Lennon, ẹni to tun sunmọ awọn oludasilẹ ẹgbẹ ajafẹtọ n ni, English Defence League, ẹni to n lo inagijẹ Tommy Robinson.

Oriṣiriṣi ayederu iroyin lo n fo kaakiri ori ayelujara, to si tan kalẹ kọja sisọ.

Joe Mulhall to jẹ alakoso ẹgbẹ oluwadii ti wọn pe ni: Hope not Hate sọ pe ko tii sẹni to n ti awọn eeyan lẹyin.

“Eyi lo ṣafihan ohun ti awọn eeyan n ṣe.

Ọpọ awọn eeyan lo n darapọ mọ iwa yii lori ayelujara, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹgbẹ tabi agbekalẹ ilana kankan - bẹẹ si ni ko si awọn olori tabi adari kankan, bo tilẹ jẹ pe awọn alẹnulọrọ ori ayelujara lo n dari wọn.

Niṣe lo dabi ile-ẹkọ Ẹ̀já, eyi ti kii ṣe ojulowo."

Iwa ẹlẹyamẹya ati gbigbe ilu ti kii ṣe t'ẹni....

Ni gbara ti eto idibo ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ ninu oṣu keje ni oriṣiriṣi akori ọrọ ti bẹrẹ sii jẹyọ bii awọn to n wa gbe nibẹ ati awọn to n wọ ọkọ oju omi wa sibẹ lati gbe.

Nigel Farage, to jẹ ọkan lara awọn gbajumọ ninu ipolongo Brexit, naa tun ti pada si oṣelu gẹgẹ bii adari ẹgbẹ oṣelu Reform UK, eyi to ti n pe fun lile awọn ti kii ṣe ọmọ ilu danu.

Ni idahun si wahala to n ṣẹlẹ, O sọ pe "pupọ lara awọn iṣoro ti wọn ni lawọn ero to n wọnu ilu wa, ti ko si si ilana fun wọn nipa wiwọle wọn."

Awọn ẹri si ti fi han pe ọpọ awọn eeyan lo ti wọ UK lọna to tọ ati ọna aitọ.

Iwadii LPSOS ninu oṣu keji sọ pe ida mejilelaadọta ni gbagbọ wa pe wọn ti wọle, to si ti pọ ju.

Ọdun meji ṣaaju asiko yii ni wọn sọ pe ida mejilelogoji ni wọn.

Bakan naa ni awọn ẹgbẹ miran bii Patriotic Alternative ti awọn naa n pe fun lile awọn to n wọnu ilu wa lọna aitọ, ti wọn si n pe fun pe ki wọn lo iwa ipa fi le wọn danu.

Awọn to n ṣagbatẹru ẹlẹyamẹya la gbọ pe wọn ti n ṣe ikọlu si awọn Mọṣalaṣi to wa niluu England, eyi to si n nilo awọn eleto aabo.

Awọn Otẹẹli ti awọn to wa aabo wa farapamọ si ti wa di ibi ti wọn doju kọ lati ṣe ikọlu si, lati le ṣe ikọlu sawọn to wa aabo wa sibẹ.

Ni apa Guusu ilu Aldershot to wa ni England, akọroyin BBC, Paddy O’Connell foju ri bi wọn ṣe n ṣe ikọlu si awọn Otẹẹli ti awọn to wa aabo wa sibẹ.

“Lori 'Facebook', wọn pe fun ifẹhonuhan alalaafia lati tọka si awọn iṣoro ile gbigbe ati ilana, eyi to dagba soke lọna to ku diẹ kaato.

Bi wọn ṣe n ju okuta, ni wọn n ju awọn nnkan miran, ti wọn si n dunkooko mọ awọn to sapamọ sibẹ fun aabo,” O sọ ninu ọrọ rẹ lori ayelujara ti BBC.

Ni iwaju ita, o ba awọn obinrin ẹgbẹ ati aburo ti wọn wa lati ilu Afghanistan sọrọ nipa idi ti wọn fi wa aabo wa si ilẹ Gẹẹsi.

“Awọn to n fa wahala yii kan de lojiji ni, wọn si gbe awọn mọto wọn sibẹ.

Wọn n gbiyanju lati gun ogiri Otẹẹli naa lati ja wọle, wọn fẹẹ ja ilẹkun, wọn si fọ ogiri ati ferese lati le wọle. Ibẹrubojo lo jẹ fun wa,” ọkan lara awọn obinrin naa to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun sọ fun akọroyin BBC.

Jija ile itaja lati ko ẹru

Awọn olufẹhonuhan tun ti lo anfaani eto yii lati bẹrẹ sii fi ja ile itaja lati ko ẹru lawọn agbegbe ti ikọlu ti n waye.

Ni Sunderland, ilu to wa lẹkun Ariwa-Guugu ilẹ Gẹẹsi, ẹka ti Greggs at ile ifowopamọ NatWest ni wọn ja, ti wọn si ko ẹru nibẹ, bakan naa ni iroyin tun gbe nipa bi wọn ṣe ja awọn ile itaja igbalode kan ni Blackpool, ninu iwadii ti awọn ọlọpaa n ṣe.

Bi wọn ṣe ja ṣọọbu ni Hull, naa ni wọn tun ja kaakiri, gẹgẹ bi abọ iwadii akọroyin BBC ti awọn iṣẹlẹ wọnyi ṣoju rẹ.

Nigba to n kọ ọ soju opo X rẹ, awọn alakoso ilu Sunderland sọ pe "Wọn mọ Sunderland si ibi to tutu to si konimọra lati gbe, awọn ohun to si ṣẹlẹ lalẹ oni ko fi iru idanimọ ti ilu wa ati awọn eeyan inu rẹ jẹ han.

“A maa parapọ, gẹgẹ bi a ṣe maa n ṣe, lati mu ipadabọsipo waye si awọn agbegbe wa."

Bakan naa ni wọn tun fi kun un pe: “Awọn nnkan bayii maa n ni ipalara si igbe aye awọn eyan, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ yii ga"

Mohammed Idris, to ni Bash café, ni South Belfast, sọ pe oun ko nii ṣilẹkun pada lẹyin ikọlu ti wọn ṣe si okoowo oun lọjọ Aiku.

Ọgbẹni Idris sọ fun BBC pe okoowo oun jẹ ibi ti wọn ti dajusọ tẹlẹ, to si ni ile itaja oun to wa ni Sandy Row ni wọn ṣe ikọlu si lọdun to kọja.

“Ile itaja ẹrọ kọmputa mi ni wọn bajẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ba ibi yii jẹ.

Café yii ni ibi ireti mi, ibi ti mo n lo fun agbegbe - ko wa tun si ireti kankan mọ bayii."

Adinku ninu iranwọ

Awọn ẹgbẹ kan ti tọka si awọn ipenija to ti jẹyọ lati ara iru awọn iṣẹlẹ ikọlu bayii, ati ọwọ ti ijọba fi mu wọn nipa awọn eleto aabo ibilẹ.

Lẹyin ikọlu to waye ni Southport, ẹgbẹ 'Hope Not Hate' sọ pe wọn ti doju iṣọkan bọlẹ latari awọn ohun to nṣẹlẹ fun ọpọlọpọ ọdun labẹ iṣakoso yii.

"O ṣe pataki ki ijọba ṣagbekalẹ awọn ọna miran lati ṣe iranwọ fun awọn agbegbe to lagbara, ati ọna ti wọn yoo gba lati maa da si iru awọn iṣẹlẹ bayii, to ba waye," wọn fi kun un.

Lọdun 2010 si ọdun 2019, lasiko iṣakoso Chancellor George Osborne ati ẹni to gba ipo lọwọ rẹ pa owo to to £30bn ($38bn) wọle ninu adinku owo ti wọn fi n ṣe iranwọ fun araalu, ati owo ori ile gbigbe ati igbe aye.

Agbeyẹwo ti Mark Easton, Olootu ile ṣe

Ni agbeyẹwo si iru awọn iṣẹlẹ ajalu buruku to ti waye sẹyin, a nilo idariji lati lero wi pe orileede n tapa si ofin, to si n buru sii.

Ṣugbọn ti ẹ ba beere lọwọ awọm eeyan nipa iriri wọn nipa iwa ọdaran, idakeji ni yoo jẹ, gẹgẹ bi abọ iwadii ti Crime Survey tilẹ England ati Wales ṣe.

Ni Sunderland, niṣe lo dabi ẹni pe awọn diẹ ni wọn ri ohun to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja, anfaani lati fi ibinu han si ipinlẹ ti wón lero wi pe o pa wọn ti sẹgbẹ kan.

Fun awọn miran, kii ṣe ohun to n ṣẹlẹ ni gbogbo igba.

Lasiko diẹ ki iṣẹlẹ ajalu naa waye, wọn ti ọkọ reluwee kan ni Glasgow, Scotland, awọn ọkunrin giriwo ni wọn tii.

Ni ita ọkọ reluwee ọhun, awọn eeyan ki wọn ku iṣẹ takuntakun ni ede guusu.

Mo ṣakiyesi oju wọn, ti a le ṣapejuwe wọn si awọn ti English Defence League tigbakan - ki ṣe igba akọkọ ree ti irufẹẹ nnkan bayii maa waye fun bi ọdun marundinlaadọta nilẹ Gẹẹsi.