Wó ìdí tí àwọn akẹgbẹ́ Uchechi Nwachukwe ṣé ṣekúpa á ní Owerri

Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn meji lori iku ọdọmọbinrin kan, Uchechi Nwachuwe, eyi ti iroyin ni awọn akẹgbẹ rẹ lo ṣekupa, ti wọn si gbe sin si ẹyin ọfisi afẹfẹ gaasi kan nipinlẹ Imo.

Mọnija ati akọwe ileeṣẹ ọhun ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayi lẹyin ti awọn mọlẹbi oloogbe naa kesi awọn ọlọpaa pe ajọmọ awọn akẹgbẹ Uchechi ni lati ṣekupa nitori o ni oun kopa ninu lilu ileeṣẹ ti wọn ti sisẹ ni jibiti.

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa safihan ibi ti wọn sin Uchechi Nwachukwe si lẹyin ti wọn ṣekupa, eyi to jẹ ẹyin ileeṣẹ ọhun niluu Owerri.

Bawo ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sawari oku Uchechi Nwachukwe?

Nigba to n sọrọ lọjọ aje, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo, CSP Michael Abattam ni oloogbe Nwachukwu kuro nile lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa ọdun 2022, ti ko si pada sile lati igba naa.

Abattam ni awọn ri oku Nwachukwu ni bi ti wọn sin si ẹyin ọfisi ileeṣẹ naa to ti n sisẹ lẹyin ọpọlọpọ iwadii ileeṣẹ ọlọpaa.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni dẹkun nibi iwadii wọn lati ri pe ọwọ tẹ awọn meji yooku to fi fẹsẹ fẹ bayii

“Kete ti awọn mọlẹbi Nwachukwu kesi wa ni a ti bẹrẹ iwadii lori ọmọ wọn, Joy Uchechi Nwachukwu, to sọnu, to jade nile lati lọ si ibi isẹ ni ileeṣẹ afẹfẹ gaasi, eyi ti orukọ rẹ njẹ, Synergy Cooking Gas, ti ko si pada sile mọ.

“Nibi ti a ti n ṣe iwadii ni a ti sawari pe awọn ti sin ọdọmọmọbinrin ọhun si ẹyin ileeṣẹ naaa. A ti wa gbe oku naa lọ si ile wọsan fun awọn iwadii miiran.

“Iwadii wa ko ti pari, a si n ṣe akitiyan lati ri pe a ri awọn yooku to ti salọ mu, ki a si fi wọn jofin.”