You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Laide Bakare di amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fọ́rọ̀ àṣà fún Gómìnà Adeleke, aáwọ̀ bẹ̀rẹ̀ láàrin òun àti Portable
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kede gbajugbaja oṣerebinrin, Laide Bakare gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ si Gomina lori ere idaraya, asa ati irinajo igbafẹ.
Bakare kede ipo tuntun yii lori opo ayelujara rẹ pẹlu aworan rẹ pẹlu Gomina Ademola Adeleke.
Ninu ọrọ rẹ to fi sita lori ayelujara, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, to si tun ṣe ileri lati saa gbogbo akitiyan lati mu aṣeyọri ba ijọba ipinlẹ Osun.
“Ni bayii, mo ti di Honourable, ya Allah mo dupẹ.”
Bakan naa lo dupẹ lọwọ Gomina Ademola Adeleke fun anfani lati wulo fun ipinlẹ Osun."
"Igba ọtun ree lati bẹrẹ irinajo oṣelu mi, ọpọ iṣẹ lo wa lati ṣe"
Laide Bakare tẹsiwaju pe “Si ọga mi tuntun, Gomina Ademola Adeleke Imole Osun, mo dupẹ gidi gan an fun bi ẹ ṣe fi ọkan tọ mi .
“Mo ṣe ileri lati sa gbogbo agbara mi, ki Ọlọrun ran mi lọwọ.
“Ọpọ iṣẹ lo wa lati ṣe, ṣe ka bẹrẹ? Igba ọtun ree lati bẹrẹ irinajo oṣelu mi. Ki Ọlọrun bu ọla fun Naijiria.
Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ bii Muka Ray. Funke Etti, Fausat Balogun, Yomi Fabiyi, Femi Adebayo ati Bimbo Oshin lo ti ransẹ ikini ku orire si Laide Bakare.
Ki lo de ti Portable fi sọko ọrọ si Laide Bakare?
Gbajugbaja olorin takasufe, Habib Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable, ti sọko ọrọ si gbajugbaja oṣere tiata, Laide Bakare lori ayelujara.
Isẹlẹ naa ko sẹyin ifọrọwerọ kan ti Laide Bakare ṣe pẹlu Biola Adebayo lori ayelujara, nibi to ti salaye oun to pa oun ati Portable papọ.
Laide ni igba ti oun pari ile oun ni Lekki, oun fi iwe ransẹ si awọn eeyan kan lati wa ba oun ṣe ajọyọ sugbọn ọpọ ni ko kọbi ara si, to fi mọ Portable.
O fikun pe nigba ti oun ra ọkọ tuntun ni Portable ba fesi lori fọnran ti o n gbe sita pe “Pẹlẹ iya olowo”.
“Ṣe ẹ ri, lori ayejura yii, awọn eeyan ni anfani lati sọ ohun ti wọn ba fẹ, ni ọmọ oloorun kan lati Sango, fi le ni anfani lati ba mi sọrọ, ti mo kan dẹ fi silẹ.
“O ni oun ko gbọdọ ri iyawo oun lẹgbẹ mi mọ ati awọn ọrọ kugbakugba mii to sọ."
Portable ni oun yoo tu asiri Laide Bakare sita lori ayelujara
Ọrọ ti Laide Bakare sọ ninu ifọrọwerọ naa, ni ko ba Portable lara mu, to si bọ sori opo ayelujara rẹ lati fesi pada.
Portable ni “Emi ni o n pe ni oloorun lati Sango, emi onidọti lati Sango to n bẹ ninu loju opo mi pe ki wa si ibi ọjọbi rẹ.
“Ọmọ oro ni mi, o le wa ma fi kọ bodi, ẹ mọ nnkan ti ẹ n ṣe o.
“Ki ni ẹ ti jẹ ninu aye, maa tu asiri yin lori opo Instagram.
“Laide Bakare, gbogbo atẹjisẹ ti ẹ fi ransẹ si mi, gbogbo ẹ ni a ma gbe sita.
“Ẹ fẹ fi wa gbadun, awa naa maa fi yin gbadun.”
Portable tun sọ awọn oko ọrọ miran ti ko wu eti gbọ si Laide Bakare, to si ni oun yoo gbe awọn ẹri sita.