You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òkùnkùn birimù gbalẹ̀ ní Spain àti Portugal, lẹ́yìn tí iná mọ̀nà-mọ́ná déèdéè lọ
Inu okunkun birimu ni awọn agbegbe kan ni orilẹede Spain ati Portugal, wa bayii lẹyin ti ina deede lọ.
Iṣẹlẹ naa to kan awọn pupọ ninu awọn agbegbe to w ani orilẹede mejeeji, mu ki awọn baalu o ma le fo, irinajo ọkọ oju irin naa dawọ duro, bẹẹ ni lilọ-bibọ ọkọ paapaa, ko ja geere nitori pe ina ojupopo ko ṣiṣẹ.
Yatọ si awọn ibi wọn yii, awọn ileewosan ko ri iṣẹ ṣe, bẹẹni awọn inu ile, ati ile itaja naa ko ri ina lo.
Titi di akoko yii, awọn alasẹ orilẹede mejeeji ko ti i le sọ pato nnkan to fa bi ina ṣe lọ. Awọn iroyin kan n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ikọlu ori ayelujara, cyber-attack, ni.
Ni nnkan bi aago mejila ọsan ku iṣẹju mẹwaa, ni ina lọ.
Pedro Sánchez, olootu orilẹede Spain, ti sọ pe ki awọn araalu rọra maa lo foonu wọn lasiko yii, nitori adanwo to ti ba awọn irinṣẹ ibanisọrọ lorilẹede naa.
O ni ki wọn o lo foonu wọn fun ipe to ṣe koko, ti ko si ni i pẹrara titi atunṣe yoo fi waye.