You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oníbàràndà gún akẹgbẹ́ rẹ̀ pa nítorí 8,000 n'Idumota Eko, ọ̀rọ̀ di bóò lọ yàgò fún mi
Ija kan to bẹ silẹ ni agbegbe Mandillas ninu ọja Balogun/Idumota nipinlẹ Eko ti gba ẹmi ọlọja kan, Sodiq Ibrahim lọjọbọ.
Ohun taa gbọ ni pe Ibrahim ni Ebuka Adindu gun lọbẹ pa lori ija to bẹ silẹ lori pe wọn fẹ pin ẹgbẹrun mẹjọ naira.
Iṣẹlẹ yii fa ibẹru-bojo ninu ọja Balogun, ti ọpọ ontaja si ni lati ti sọọbu wọn pa lọjọ naa.
Ṣaaju ni iroyin n lọ kiri pe ija ẹlẹyamẹya lo bẹ silẹ ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti wọgile erongba naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin ni, "Lasiko ija naa, Ebuka Adindu lati ipinlẹ Abia gun Sodiq Ibrahim lati Kogi lọbẹ pa.
Hundeyin sọ pe awọn ti fi panpẹ ofin mu u mọ ileewosan to wa, ti iwadii si n lọ lọwọ."
Ileeṣẹ iroyin abẹle PUNCH jabọ pe awọn ọkunrin meji naa jẹ ọmọ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni 'Oso Ahia', eyi ti wọn n pe ni baranda ni ede Yoruba.
Iṣẹ wọn ni pe ki wọn mu onibaara lati ojupopo tabi aarin ọja wa sinu sọọbu, ti wọn yoo si gba ere diẹ.
Bawo ni iṣẹlẹ yii ṣe waye?
Ija yii bẹ silẹ nigba ti oni sọọbu kan fun awọn mejeeji ni ẹgbẹrun mẹjọ pe ki wọn pin owo naa laarin ara wọn.
Ọlọja kan ninu ọja naa, Funmi Arewa, fidi eyii mulẹ fun ileeṣẹ iroyin abẹle PUNCH.
"Awọn mejeeji jẹ awọn to ma n mu onibaara wa si sọọbu lati wa ra ọja, ti wọn yoo si gba owo wọn.
"Awọn mejeeji mu eeyan kan naa wa, ti oni sọọbu si fun wọn ni ẹgbẹrun mẹjọ pe ki wọn pin laaarin ara wọn. Ibẹ ni wahala ti bẹ silẹ.
"Wọn bẹrẹ si ni i ṣe ariyanjiyan lori bi wọn yoo ṣe pin owo naa, ibi ti wọn ti n ja ni ọkan ti gun ọkan lọbẹ. O ṣeeṣe ko ma ni erongba lati pa a ṣugbọn o ṣe ni laanu pe ọmọ naa ku."
Ọlọja mii, Chigozie, ṣalaye fun awọn akọroyin pe oloogbe lo kọkọ gun Adindu pẹlu igo, to si sa lọ pẹlu ero pe ọwọ ikeji ko ni ba a.
"Adindu le oloogbe pẹlu ọbẹ, ti oun naa si gun lọbẹ, to sokunfa iku rẹ," Chigozie ṣalaye.