You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti afárá Third mainland wò ọ̀nà míì tí o lè gbà láti sá fún ìgbòkègbodò ọ̀kọ̀
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede eto lati dari irinna ọkọ lori afara Third mainland lọjọ Aiku, lati bẹrẹ atunṣe si awọn apa ibi kan lori afara naa ti o nilo atunṣe kiakia.
Komisona to wa fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Ọmọwe Frederick Oladeinde, ṣalaye eyi ninu iroyin to fi lede.
Oladeinde ni atunṣe naa yo bẹrẹ laago mẹsan aarọ si aago mẹrin irọlẹ ọjọ Aiku.
Kọmisọna ninu atẹjade naa sọ wi pe “igbokegbodo ọkọ yoo yipada lori afara Third Mainland lati apa oju-ọna kan si apa oju ọna miiran.
Eyi ṣe pataki lati din sunkẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ ku lopopona ọhun.
Kọmisona tun ni "Mo tun fẹ lati ṣe idaniloju fun awọn ara ilu pe ajọ ijọba ipinlẹ Eko to n ṣamojuto igbokegbodo ọkọ yoo wa ni arọwọto lati dari irinna.
“Mo si rọ awọn to n rin lọna lati ni suuru nitori awọn igbesẹ ti a pese silẹ yoo mu ki opopona naa wa ni ailewu fun awọn to n rin ọna naa.
Oladeinde wa fi da awọn eeyan loju pe awọn ẹsọ oju popo yoo wa nilẹ lati ṣe amojuto bi ko ṣe ni si sunkẹrẹ-fakẹrẹ lasiko ti atunṣe naa n lọ lọwọ.
Bakan naa lo rọ awọn Awakọ lati ṣe suuru lasiko ti wọn ba gba oju ọna ọhun.