Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó ní òun yóò kó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB lọ sílùú Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin to pe ara rẹ ni Eze ti Ajao Estate niluu Eko, Fredrick Nwajagu.

Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti afurasi ọhun fi fidio kan lede lori ayelujara, nibi to ti sọ pe oun yoo fiwe pe awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara IPOB lati wa siluu Eko.

O ni eredi ti oun yoo fi ṣe bẹẹ ni lati daabo bo awọn ọmọ Igbo to wa niluu Eko.

Ọwọ ofin tẹ Nwajagu lẹyin ifọwọsowọpọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati ileeṣẹ ọlọpaa.

Ki ni Fredrick Nwajagu sọ ṣaaju?

Nwajagu ni “Awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB ti a o fiwe pe n bọ, o wa lara awọn nnkan ti a fẹ ṣe fun wọn, a o fun wọn niṣẹ.”

“Wọn ko niṣẹ lọwọ, a o pe awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB wa lati maa ṣọ awọn ṣọọbu wa, ti a o si maa san owo fun wọn.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn yoo pe awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB naa wa lati maa dabo bo awọn ṣọọbu ati ileeṣẹ awọn ọmọ ẹya Igbo niluu Eko.

O ni “A o pe awọn ọmọ IPOB naa wa lati dabo bo wa ki wọn ma ba maa ṣakọlu si wa mọ lọganjọ oru.”

“Mi o le maa fi ọrọ sabẹ ahọn sọ, awọn ọmọ Igbo gbọdọ gba ẹtọ wọn lati da duro niluu Eko.”

Ọlọpaa fesi

Ẹwẹ, ni kete ti ileeṣẹ ọlọpaa Eko gbọ ọrọ naa ni wọn bẹrẹ iṣẹ lati fi ṣikun ofin mu ọkunrin ọhun.

Ninu ọrọ rẹ loju opo Twitter, alukoro ileeṣẹ naa, Benjamin Hundeyin sọ pe awọn ko ni la oju awọn silẹ ki awọn kọlọrọsi kan da ilu ru mọ awọn lori.

Hundeyin ni “Lakọkọ na, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ko ni kawọ gbera ko gba irufẹ nnkan bayii laaye lati wa si imuṣẹ niluu Eko.

Ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọrọ naa.

Lati igba ti esi ibo Aarẹ Naijiria ti jade, ti Bola Tinubu lulẹ nigba ti Peter Obi bori niluu Eko ni họwuhọwu ti n waye laarin ẹya Igbo ati Yoruba nipinlẹ naa.