You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Nàìjíríà kéde ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti ṣèbúra fún Tinubu láti ṣèbúra fún Tinubu
Ijọba orilẹede Naijiria ti kede Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023 gẹgẹ bi ọjọ Isinmi fun awọn araalu lati burawọle fun aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Ahmed Tinubu.
Minisita fun ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Aregbesola to kede ọjọ isinmi naa, ni ọjọ naa wa fun ayẹyẹ ọjọ ominira Naijiria.
Saaju ni ọjọ naa jẹ ojọ isinmi ki aarẹ Buhari to sun Ayajọ Ọjọ ominira Naijiria si Ọjọ Kejila, Osu Kẹfa, ọdọọdun.
Amọ ko i tii daju bọya awọn araalu yoo tun gba ọjọ isinmi miran ni ọjọ June 12.
Nigba ti aare Buhari sun ọjọ naa ni ọdun 2018 ni oun gbe igbesẹ naa lati bu ọla fun Moshood Abiola to jawe olubori ninu idibo ọdun June 12, 1993 amọ ti ijọba ologun doju rẹ bolẹ nigba naa lọhun.
Awọn ẹṣọ alaabo ni ohun gbogbo lo ti wa ni pẹṣẹ fun eto iburawọle ti yoo waye ni ilu Abuja.
Tinubu ni yoo jẹ aarẹ kẹrindinlogun ti wọn yoo maa dibo yan gẹgẹ bi aarẹ ni ijọba alagbada ni orilẹede Naijiria.